Kol 3:5-17

Kol 3:5-17 YBCV

Nitorina ẹ mã pa ẹ̀ya-ara nyin ti mbẹ li aiye run: àgbere, iwa-ẽri, ifẹkufẹ, ifẹ buburu, ati ojukòkoro, ti iṣe ibọriṣa: Nitori ohun tí ibinu Ọlọrun fi mbọ̀wa sori awọn ọmọ alaigbọran. Ninu eyiti ẹnyin pẹlu ti nrìn nigbakan rí, nigbati ẹnyin ti wà ninu nkan wọnyi. Ṣugbọn nisisiyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu; ibinu, irunu, arankàn, ọrọ-odi, ati ọrọ itiju kuro li ẹnu nyin. Ẹ má si ṣe purọ́ fun ẹnikeji nyin, ẹnyin sa ti bọ́ ogbologbo ọkunrin nì silẹ pẹlu iṣe rẹ̀; Ẹ si ti gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a sọ di titun si ìmọ gẹgẹ bi aworan ẹniti o da a: Nibiti kò le si Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira: ṣugbọn Kristi li ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo. Nitorina, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ́ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nu wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutù, ipamọra; Ẹ mã farada a fun ara nyin, ẹ si mã dariji ara nyin bi ẹnikẹni bá ni ẹ̀sun si ẹnikan: bi Kristi ti darijì nyin, gẹgẹ bẹ̃ni ki ẹnyin ki o mã ṣe pẹlu. Ati bori gbogbo nkan wọnyi, ẹ gbé ifẹ wọ̀, ti iṣe àmure ìwa pipé. Ẹ si jẹ ki alafia Ọlọrun ki o mã ṣe akoso ọkàn nyin, sinu eyiti a pè nyin pẹlu ninu ara kan; ki ẹ si ma dupẹ. Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa. Ohunkohun ti ẹnyin ba si nṣe li ọ̀rọ tabi ni iṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn li orukọ Jesu Oluwa, ẹ mã fi ọpẹ́ fun Ọlọrun Baba nipasẹ rẹ̀.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Kol 3:5-17