Nitori eyi, lati ọjọ ti awa ti gbọ, awa pẹlu kò simi lati mã gbadura ati lati mã bẹ̀bẹ fun nyin pe ki ẹnyin ki o le kún fun ìmọ ifẹ rẹ̀ ninu ọgbọ́n ati imoye gbogbo ti iṣe ti Ẹmí;
Ki ẹ le mã rìn ni yiyẹ niti Oluwa si ìwu gbogbo, ki ẹ ma so eso ninu iṣẹ rere gbogbo, ki ẹ si mã pọ si i ninu ìmọ Ọlọrun;
Ki a fi ipá gbogbo sọ nyin di alagbara, gẹgẹ bi agbara ogo rẹ̀, sinu suru ati ipamọra gbogbo pẹlu ayọ̀;
Ki a mã dupẹ lọwọ Baba, ẹniti o mu wa yẹ lati jẹ alabapin ninu ogún awọn enia mimọ́ ninu imọlẹ:
Ẹniti o ti gbà wa kuro lọwọ agbara òkunkun, ti o si ṣi wa nipo sinu ijọba ayanfẹ ọmọ rẹ̀:
Ninu ẹniti awa ni idande nipa ẹ̀jẹ rẹ̀, ani idariji ẹ̀ṣẹ:
Ẹniti iṣe aworan Ọlọrun ti a kò ri, akọbi gbogbo ẹda:
Nitori ninu rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ohun ti mbẹ li ọrun, ati ohun ti mbẹ li aiye, eyiti a ri, ati eyiti a kò ri, nwọn iba ṣe itẹ́, tabi oye, tabi ijọba, tabi ọla: nipasẹ rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ati fun u:
On si wà ṣaju ohun gbogbo, ati ninu rẹ̀ li ohun gbogbo duro ṣọkan.
On si jẹ ori fun ara, eyini ni ìjọ: ẹniti iṣe ipilẹṣẹ, akọbi lati inu okú wá; pe, ninu ohun gbogbo ki on ki o le ni ipò ti o ga julọ.
Nitori didun inu Baba ni pe ki ẹkún gbogbo le mã gbé inu rẹ̀;
Ati nipasẹ rẹ̀ lati bá ohun gbogbo lajà, lẹhin ti o ti fi ẹjẹ agbelebu rẹ̀ pari ija; mo ni, nipasẹ rẹ̀, nwọn iba ṣe ohun ti mbẹ li aiye, tabi ohun ti mbẹ li ọrun.
Ati ẹnyin ti o ti jẹ alejò ati ọtá rí li ọkàn nyin ni iṣẹ buburu nyin, ẹnyin li o si ti bá laja nisisiyi,
Ninu ara rẹ̀ nipa ikú, lati mu nyin wá iwaju rẹ̀ ni mimọ́ ati ailabawọn ati ainibawi;
Bi ẹnyin ba duro ninu igbagbọ́, ti ẹ fẹsẹmulẹ ti ẹ si duro ṣinṣin, ti ẹ kò si yẹsẹ kuro ninu ireti ihinrere ti ẹnyin ti gbọ́, eyiti a si ti wasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹda ti mbẹ labẹ ọrun, eyiti a fi emi Paulu ṣe iranṣẹ fun.
Nisisiyi emi nyọ̀ ninu ìya mi nitori nyin, emi si nmu ipọnju Kristi ti o kù lẹhin kún li ara mi, nitori ara rẹ̀, ti iṣe ìjọ:
Eyiti a fi emi ṣe iranṣẹ fun, gẹgẹ bi iṣẹ iriju Ọlọrun ti a fifun mi fun nyin lati mu ọ̀rọ Ọlọrun ṣẹ;
Ani ohun ijinlẹ ti o ti farasin lati aiyeraiye ati lati irandiran, ṣugbọn ti a ti fihàn nisisiyi fun awọn enia mimọ́ rẹ̀:
Awọn ẹniti Ọlọrun fẹ lati fi ọrọ̀ ohun ijinlẹ yi larin awọn Keferi hàn fun, ti iṣe Kristi ninu nyin, ireti ogo:
Ẹniti awa nwasu rẹ̀ ti a nkìlọ fun olukuluku enia, ti a si nkọ́ olukuluku enia ninu ọgbọ́n gbogbo; ki a le mu olukuluku enia wá ni ìwa pipé ninu Kristi Jesu:
Eyiti emi nṣe lãlã ti mo si njijakadi fun pẹlu, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, ti nfi agbara ṣiṣẹ gidigidi ninu mi.