Amo 8
8
Ìran Nípa Agbọ̀n Èso
1BAYI li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si kiyesi i, agbọ̀n eso ẹrùn kan.
2On si wipe, Amosi, kili ohun ti iwọ ri? Emi si wipe, Agbọ̀n eso ẹrùn ni. Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Opin de si Israeli enia mi; emi kì yio tún kọja lọdọ wọn mọ.
3Orin inu tempeli yio si jẹ hihu li ọjọ na, li Oluwa Ọlọrun wi: okú pupọ̀ ni yio wà ni ibi gbogbo; nwọn o ma fi idakẹ jù wọn sode.
Ìparun Israẹli
4Ẹ gbọ́ eyi, ẹnyin ti ngbe awọn alaini mì, lati sọ awọn talakà ilẹ na di alaini,
5Ti nwipe, Nigbawo ni oṣù titún yio pari, ki awa ba le ta ọkà? ati ọjọ isimi, ki awa ba le ṣi alikama silẹ, ki a si ṣe ìwọn efà kere, ati ìwọn ṣekeli tobi, ki a si ma fi ẹ̀tan yi ìwọn padà?
6Ki awa le fi fàdakà rà talakà, ati bàta ẹsẹ̀ mejeji rà alaini, ki a si tà eyiti o dànu ninu alikama?
7Oluwa ti bura nipa ọlanla Jakobu pe, Nitõtọ emi kì yio gbàgbe ọkan ninu iṣẹ wọn.
8Ilẹ na kì yio ha warìri nitori eyi, ati olukuluku ẹniti o ngbe inu rẹ̀ kì yio ha ṣọ̀fọ? yio si rú soke patapata bi kikún omi; a o si tì i jade, a o si tẹ̀ ẹ rì, gẹgẹ bi odò Egipti.
9Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa Ọlọrun wi; emi o si mu ki õrùn ki o wọ̀ lọsan, emi o si mu aiye ṣu òkunkun li ọ̀san gangan:
10Emi o si yi àse nyin padà si ọ̀fọ, ati orin nyin gbogbo si ohùn-rére ẹkún: emi o si mu aṣọ ọ̀fọ wá si ẹgbẹ̀ gbogbo, ati pipá ori, si gbogbo ori; emi o si ṣe e ki o dàbi iṣọ̀fọ fun ọmọ kanṣoṣo ti a bi; ati opin rẹ̀ bi ọjọ kikorò.
11Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa Ọlọrun wi, emi o rán iyàn wá si ilẹ na, kì iṣe iyàn onjẹ, tabi ongbẹ fun omi, ṣugbọn iyàn gbigbọ́ ọ̀rọ Oluwa:
12Nwọn o si ma rìn kiri lati okun de okun, ati lati ariwa ani titi de ila-õrun, nwọn o sare siwá sẹhìn lati wá ọ̀rọ Oluwa, nwọn kì yio si ri i.
13Li ọjọ na li awọn arẹwà wundia, ati awọn ọdọmọkunrin yio daku fun ongbẹ.
14Awọn ti o fi ẹ̀ṣẹ Samaria bura, ti nwọn si wipe, Iwọ Dani, ọlọrun rẹ mbẹ lãyè! ati ọ̀na Beerṣeba mbẹ lãyè! ani nwọn o ṣubu, nwọn kì yio si tún dide mọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Amo 8: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.