Amo 5

5
Ìpè sí Ìrònúpìwàdà
1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ yi ti emi gbe soke si nyin, ani ohùnrére ẹkun, ẹnyin ile Israeli.
2Wundia Israeli ti ṣubu; kì yio dide mọ: a kọ̀ ọ silẹ lori ilẹ rẹ̀; kò si ẹniti yio gbe e dide.
3Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ilu ti o jade lọ li ẹgbẹrun yio ṣikù ọgọrun; eyiti o si jade lọ li ọgọrun yio ṣikù mẹwa, fun ile Israeli.
4Nitori bayi li Oluwa wi fun ile Israeli, ẹ wá mi, ẹnyin o si yè:
5Ṣugbọn ẹ máṣe wá Beteli, bẹ̃ni ki ẹ má wọ̀ inu Gilgali lọ, ẹ má si rekọja lọ si Beerṣeba: nitori lõtọ Gilgali yio lọ si igbèkun, Beteli yio si di asan.
6Ẹ wá Oluwa, ẹnyin o si yè; ki o má ba gbilẹ bi iná ni ile Josefu, a si jó o run, ti kì o fi si ẹnikan lati pá a ni Beteli.
7Ẹnyin ti ẹ sọ idajọ di iwọ, ti ẹ si kọ̀ ododo silẹ li aiye.
8Ẹ wá ẹniti o dá irawọ̀ meje nì ati Orioni, ti o si sọ ojiji ikú di owurọ̀, ti o si fi oru mu ọjọ ṣokùnkun: ti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade soju aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀:
9Ti o mu iparun kọ manà sori alagbara, tobẹ̃ ti iparun yio wá si odi agbara.
10Nwọn korira ẹniti nbaniwi li ẹnu bodè, nwọn si korira ẹniti nsọ otitọ.
11Nitorina niwọ̀n bi itẹ̀mọlẹ nyin ti wà lori talakà, ti ẹnyin si gba ẹrù alikama lọwọ rẹ̀: ẹnyin ti fi okuta ti a gbẹ́ kọ́ ile, ṣugbọn ẹ kì o gbe inu wọn; ẹnyin ti gbìn ọgbà àjara daradara, ṣugbọn ẹ kì o mu ọti-waini wọn.
12Nitori mo mọ̀ onirũru irekọja nyin, ati ẹ̀ṣẹ nla nyin: nwọn npọ́n olododo loju, nwọn ngbà owo abẹ̀tẹlẹ, nwọn si nyi awọn talakà si apakan ni bodè, kuro ninu are wọn.
13Nitorina ẹni-oye yio dakẹ nigbana; nitori akòko ibi ni.
14Ẹ ma wá ire, kì isi iṣe ibi, ki ẹ ba le yè; bẹ̃ni Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, yio si pẹlu nyin, bi ẹnyin ti wi.
15Ẹ korira ibi, ẹ si fẹ́ ire, ki ẹ si fi idajọ gunlẹ ni bodè; boya Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun yio ṣe ojurere si iyokù Josefu.
16Nitorina Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ani Oluwa wi bayi pe, Ẹkun yio wà ni gbogbo ita; nwọn o si ma wi ni gbogbo òpopó ọ̀na pe, Ã! ã! nwọn o si pè agbẹ̀ si iṣọ̀fọ, ati iru awọn ti o gbọ́n lati pohùnrére si isọkún.
17Ati ni gbogbo ọ̀gba àjara ni isọkún yio gbe wà: nitori emi o kọja lãrin rẹ, li Oluwa wi.
18Egbe ni fun ẹnyin ti ẹ nfẹ́ ọjọ Oluwa! kili eyi o jasi fun nyin? ọjọ Oluwa òkunkun ni, kì isi iṣe imọlẹ.
19Gẹgẹ bi enia ti o sa fun kiniun, ti beari si pade rẹ̀; tabi ti o wọ̀ inu ile, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ tì lara ogiri, ti ejò si bù u jẹ.
20Ọjọ Oluwa kì o ha ṣe òkunkun laiṣe imọlẹ? ani òkunkun biribiri, laisi imọlẹ ninu rẹ̀?
21Mo korira, mo si kẹgàn ọjọ asè nyin, emi kì o si gbõrùn ọjọ ajọ ọ̀wọ nyin.
22Bi ẹnyin tilẹ rú ẹbọ sisun ati ẹbọ jijẹ nyin si mi, emi kì o si gbà wọn: bẹ̃ni emi ki yio nani ẹbọ ọpẹ́ ẹran abọ́pa nyin.
23Mu ariwo orin rẹ kuro lọdọ mi; nitori emi kì o gbọ́ iró adùn fioli rẹ.
24Ṣugbọn jẹ ki idajọ ki o ṣàn silẹ bi omi, ati ododo bi iṣàn omi nla.
25Ẹnyin ha ti rubọ si mi, ẹ ha ti ta mi lọrẹ li aginjù li ogoji ọdun, ẹnyin ile Israeli.
26Ṣugbọn ẹnyin ti rù agọ Moloku ati Kiuni nyin, awọn ere nyin, irawọ̀ òriṣa nyin, ti ẹ ṣe fun ara nyin.
27Nitorina, emi o mu ki ẹ lọ si igbèkun rekọja Damasku, li Oluwa wi, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Amo 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀