Amo 1:3-15

Amo 1:3-15 YBCV

Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Damasku, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti fi ohunèlo irin ipakà pa Gileadi: Ṣugbọn emi o rán iná kan si ile Hasaeli, ti yio jo ãfin Benhadadi wọnni run. Emi o ṣẹ ọpá idabu Damasku pẹlu, emi o si ke ará pẹ̀tẹlẹ Afeni kuro, ati ẹniti o dì ọpá alade nì mu kuro ni ile Edeni: awọn enia Siria yio si lọ si igbèkun si Kiri, ni Oluwa wi. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Gasa, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti kó gbogbo igbèkun ni igbèkun lọ, lati fi wọn le Edomu lọwọ. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Gasa, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run: Emi o si ke ara Aṣdodi kuro, ati ẹniti o di ọpá alade mu kuro ni Aṣkeloni, emi o si yi ọwọ́ mi si Ekroni; iyokù ninu awọn ara Filistia yio ṣegbe, li Oluwa Ọlọrun wi. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Tire, ati nitori mẹrin: emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn fi gbogbo igbèkun le Edomu lọwọ, nwọn kò si ranti majẹmu arakunrin. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Tire, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Edomu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o fi idà lepa arakunrin rẹ̀, o si gbe gbogbo ãnu sọnù; ibinu rẹ̀ si nfaniya titi, o si pa ibinu rẹ̀ mọ titi lai. Ṣugbọn emi o rán iná kan si Temani, ti yio jó afin Bosra wọnni run. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti awọn ọmọ Ammoni, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti là inu awọn aboyun Gileadi, ki nwọn le ba mu agbègbe wọn tobi: Ṣugbọn emi o da iná kan ninu odi Rabba, yio si jó ãfin rẹ̀ wọnni run, pẹlu iho ayọ̀ li ọjọ ogun, pẹlu ijì li ọjọ ãjà: Ọba wọn o si lọ si igbèkun, on ati awọn ọmọ-alade rẹ̀ pọ̀, li Oluwa wi.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa