Amo 1:3-15

Amo 1:3-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Damasku, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti fi ohunèlo irin ipakà pa Gileadi: Ṣugbọn emi o rán iná kan si ile Hasaeli, ti yio jo ãfin Benhadadi wọnni run. Emi o ṣẹ ọpá idabu Damasku pẹlu, emi o si ke ará pẹ̀tẹlẹ Afeni kuro, ati ẹniti o dì ọpá alade nì mu kuro ni ile Edeni: awọn enia Siria yio si lọ si igbèkun si Kiri, ni Oluwa wi. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Gasa, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti kó gbogbo igbèkun ni igbèkun lọ, lati fi wọn le Edomu lọwọ. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Gasa, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run: Emi o si ke ara Aṣdodi kuro, ati ẹniti o di ọpá alade mu kuro ni Aṣkeloni, emi o si yi ọwọ́ mi si Ekroni; iyokù ninu awọn ara Filistia yio ṣegbe, li Oluwa Ọlọrun wi. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Tire, ati nitori mẹrin: emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn fi gbogbo igbèkun le Edomu lọwọ, nwọn kò si ranti majẹmu arakunrin. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Tire, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Edomu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o fi idà lepa arakunrin rẹ̀, o si gbe gbogbo ãnu sọnù; ibinu rẹ̀ si nfaniya titi, o si pa ibinu rẹ̀ mọ titi lai. Ṣugbọn emi o rán iná kan si Temani, ti yio jó afin Bosra wọnni run. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti awọn ọmọ Ammoni, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti là inu awọn aboyun Gileadi, ki nwọn le ba mu agbègbe wọn tobi: Ṣugbọn emi o da iná kan ninu odi Rabba, yio si jó ãfin rẹ̀ wọnni run, pẹlu iho ayọ̀ li ọjọ ogun, pẹlu ijì li ọjọ ãjà: Ọba wọn o si lọ si igbèkun, on ati awọn ọmọ-alade rẹ̀ pọ̀, li Oluwa wi.

Amo 1:3-15 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Àwọn ará Damasku ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà. Wọ́n mú ohun èlò ìpakà onírin ṣómúṣómú, wọ́n fi pa àwọn ará Gileadi ní ìpa ìkà. Nítorí náà, n óo sọ iná sí ààfin Hasaeli, yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi kanlẹ̀. N óo fọ́ ìlẹ̀kùn odi ìlú Damasku. N óo sì pa gbogbo àwọn ará àfonífojì Afeni run. Wọn óo mú ọba Betedeni lọ sí ìgbèkùn; òun ati àwọn ará Siria yóo lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Kiri.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Àwọn ará Gasa ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí odidi orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n kó lẹ́rú, tí wọ́n lọ tà fún àwọn ará Edomu. N óo sọ iná sí ìlú Gasa, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun. N óo pa gbogbo àwọn ará Aṣidodu run ati ọba Aṣikeloni; n óo jẹ ìlú Ekironi níyà, àwọn ará Filistia yòókù yóo sì ṣègbé.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Àwọn ará Tire ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n kó odidi orílẹ̀-èdè kan lẹ́rú lọ tà fún àwọn ará Edomu. Wọn kò sì ranti majẹmu tí wọ́n bá àwọn arakunrin wọn dá. Nítorí náà n óo sọ iná sí orí odi ìlú Tire, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.” OLUWA ní: “Àwọn ará Edomu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n dojú idà kọ arakunrin wọn, láìṣàánú wọn, wọ́n bínú kọjá ààlà, títí lae sì ni ìrúnú wọn. Nítorí náà, n óo rán iná sí ìlú Temani, yóo sì jó ibi ààbò Bosira ní àjórun.” OLUWA ní: “Àwọn ará Amoni ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; wọ́n fi ìwà wọ̀bìà bẹ́ inú àwọn aboyún ilẹ̀ Gileadi, láti gba ilẹ̀ kún ilẹ̀ wọn. Nítorí náà, n óo sọ iná sí orí odi ìlú Raba, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun. Ariwo yóo sọ ní ọjọ́ ogun, omi òkun yóo ru sókè ní ọjọ́ ìjì; ọba wọn ati àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo sì lọ sí ìgbèkùn.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Amo 1:3-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi. Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli Èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run. Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku; Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní Àfonífojì Afeni run àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni. Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,” ni OLúWA wí. Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gasa, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú, ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn. Ó sì tà wọ́n fún Edomu, Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò, ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú. Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,” ni OLúWA Olódùmarè wí. Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tire àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún Edomu Wọn kò sì nání májẹ̀mú ọbàkan, Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire Tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.” Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Edomu, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀, Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́ Èmi yóò rán iná sí orí Temani Tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.” Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ammoni àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gileadi kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn. Èmi yóò rán iná sí ara odi Rabba èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun, pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà. Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn Òun àti àwọn ọmọ-aládé rẹ̀ lápapọ̀,” ni OLúWA wí.