ṢUGBỌN Saulu, o nmí ẹmi ikilọ ati pipa sibẹ si awọn ọmọ-ẹhin Oluwa, o tọ̀ olori alufa lọ;
O bẽre iwe lọwọ rẹ̀ si Damasku si awọn sinagogu pe, bi on ba ri ẹnikẹni ti mbẹ li Ọna yi, iba ṣe ọkunrin, tabi obinrin, ki on le mu wọn ni didè wá si Jerusalemu.
O si ṣe, bi o ti nlọ, o si sunmọ Damasku: lojijì lati ọrun wá, imọlẹ si mọlẹ yi i ka:
O si ṣubu lulẹ, o gbọ́ ohùn ti o nfọ̀ si i pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi?
O si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi Jesu ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si: ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún.
O si nwarìri, ẹnu si yà a, o ni, Oluwa, kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe? Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ilu na, a o sọ fun ọ li ohun ti iwọ o ṣe.
Awọn ọkunrin ti nwọn si mba a re àjo duro, kẹ́kẹ pa mọ́ wọn li ẹnu, nwọn gbọ́ ohùn na, ṣugbọn nwọn kò ri ẹnikan.
Saulu si dide ni ilẹ; nigbati oju rẹ̀ si là kò ri ohunkan: ṣugbọn nwọn fà a li ọwọ́, nwọn si mu u wá si Damasku.
O si gbé ijọ mẹta li airiran, kò si jẹ, bẹ̃ni kò si mu.
Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Damasku, ti a npè ni Anania; Oluwa si wi fun u li ojuran pe, Anania. O si wipe, Wò o, emi niyi, Oluwa.
Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ita ti a npè ni Ọgãnran, ki o si bère ẹniti a npè ni Saulu, ara Tarsu, ni ile Juda: sá wo o, o ngbadura.
On si ti ri ọkunrin kan li ojuran ti a npè ni Anania o wọle, o si fi ọwọ́ le e, ki o le riran.
Anania si dahùn wipe, Oluwa, mo ti gburó ọkunrin yi lọdọ ọ̀pọ enia, gbogbo buburu ti o ṣe si awọn enia mimọ́ rẹ ni Jerusalemu.
O si gbà aṣẹ lati ọdọ awọn olori alufa wá si ihinyi, lati dè gbogbo awọn ti npè orukọ rẹ.
Ṣugbọn Oluwa wi fun u pe, Mã lọ: nitori ohun elo àyo li on jẹ fun mi, lati gbe orukọ mi lọ si iwaju awọn Keferi, ati awọn ọba, ati awọn ọmọ Israeli:
Nitori emi o fi gbogbo ìya ti kò le ṣaijẹ nitori orukọ mi han a.
Anania si lọ, o si wọ̀ ile na; nigbati o si fi ọwọ́ rẹ̀ le e, o ni, Saulu Arakunrin, Oluwa li o rán mi, Jesu ti o fi ara hàn ọ li ọ̀na ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmí Mimọ́.
Lojukanna nkan si bọ kuro li oju rẹ̀ bi ipẹpẹ́: o si riran; o si dide, a si baptisi rẹ̀.
Nigbati o si jẹun, ara rẹ̀ mokun: Saulu si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin ni Damasku ni ijọ melokan.
Lojukanna o si nwasu Kristi ninu awọn sinagogu pe, Ọmọ Ọlọrun li on iṣe.
Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o ngbọ́, nwọn si wipe, Ẹniti o ti fõro awọn ti npè orukọ yi ni Jerusalemu kọ li eyi, ti o si ti itori na wá si ihinyi, lati mu wọn ni didè lọ sọdọ awọn olori alufa?
Ṣugbọn Saulu npọ̀ si i li agbara o si ndãmu awọn Ju ti o ngbe Damasku, o nfi hàn pe, eyi ni Kristi na.
Lẹhin igbati ọjọ pipọ kọja, awọn Ju ngbìmọ lati pa a:
Ṣugbọn ìditẹ̀ wọn di mimọ̀ fun Saulu. Nwọn si nṣọ ẹnu-bode pẹlu li ọsán ati li oru lati pa a.
Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mu u li oru, nwọn si sọ̀ ọ kalẹ lara odi ninu agbọ̀n.
Nigbati Saulu si de Jerusalemu, o pete ati da ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn ọmọ-ẹhin: gbogbo nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, nitori nwọn kò gbagbọ́ pe ọmọ-ẹhin kan ni.
Ṣugbọn Barnaba mu u, o si sìn i lọ sọdọ awọn aposteli, o si sọ fun awọn bi o ti ri Oluwa li ọ̀na, ati pe o ti ba a sọ̀rọ, ati bi o ti fi igboiya wasu ni Damasku li orukọ Jesu.
O si wà pẹlu wọn, o nwọle o si njade ni Jerusalemu.
O si nfi igboiya sọ̀rọ li orukọ Jesu Oluwa, o nsọrọ lòdi si awọn ara Hellene, o si njà wọn niyàn: ṣugbọn nwọn npete ati pa a.
Nigbati awọn arakunrin si mọ̀, nwọn mu u sọkalẹ lọ si Kesarea, nwọn si rán a lọ si Tarsu.
Nigbana ni ijọ wà li alafia yi gbogbo Judea ká ati ni Galili ati ni Samaria, nwọn nfẹsẹmulẹ; nwọn nrìn ni ìbẹru Oluwa, ati ni itunu Ẹmí Mimọ́, nwọn npọ̀ si i.