Iṣe Apo 6:5-7

Iṣe Apo 6:5-7 YBCV

Ọ̀rọ na si tọ́ loju gbogbo ijọ: nwọn si yàn Stefanu, ọkunrin ti o kún fun igbagbọ́ ati fun Ẹmí Mimọ́, ati Filippi ati Prokoru, ati Nikanoru, ati Timoni, ati Parmena, ati Nikola alawọṣe Ju ara Antioku: Ẹniti nwọn mu duro niwaju awọn aposteli: nigbati nwọn si gbadura, nwọn fi ọwọ́ le wọn. Ọ̀rọ Ọlọrun si gbilẹ; iye awọn ọmọ-ẹhin si pọ̀ si i gidigidi ni Jerusalemu; ọ̀pọ ninu ẹgbẹ awọn alufa si fetisi ti igbagbọ́ na.