Nigbati nwọn si mu wọn de, nwọn mu wọn duro niwaju ajọ igbimọ; olori alufa si bi wọn lẽre,
Wipe, Awa kò ti kìlọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yi kọ́ni mọ́? si wo o, ẹnyin ti fi ẹkọ́ nyin kún Jerusalemu, ẹ si npete ati mu ẹ̀jẹ ọkunrin yi wá si ori wa.
Ṣugbọn Peteru ati awọn aposteli dahùn, nwọn si wipe, Awa kò gbọdọ má gbọ́ ti Ọlọrun jù ti enia lọ.
Ọlọrun awọn baba wa ji Jesu dide, ẹniti ẹnyin pa, tí ẹnyin si gbe kọ́ sori igi.
On li Ọlọrun fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ gbéga lati jẹ Ọmọ alade ati Olugbala, lati fi ironupiwada fun Israeli, ati idariji ẹ̀ṣẹ.
Awa si li ẹlẹri nkan wọnyi; ati Ẹmí Mimọ́ pẹlu, ti Ọlọrun fifun awọn ti o gbọ́ tirẹ̀.
Ṣugbọn nigbati nwọn gbọ́ eyi, àiya wọn gbà ọgbẹ́ de inu, nwọn gbèro ati pa wọn.
Ṣugbọn ọkan ninu ajọ igbimọ, ti a npè ni Gamalieli, Farisi ati amofin, ti o ni iyìn gidigidi lọdọ gbogbo enia, o dide duro, o ni ki a mu awọn aposteli bì sẹhin diẹ;
O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ọkunrin Israeli, ẹ kiyesi ara nyin li ohun ti ẹnyin npete ati ṣe si awọn ọkunrin wọnyi.
Nitori ṣaju ọjọ wọnyi ni Teuda dide, o nwipe ẹni nla kan li on; ẹniti ìwọn irinwo ọkunrin gbatì: ẹniti a pa; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a tú wọn ká, a si sọ wọn di asan.
Lẹhin ọkunrin yi ni Juda ti Galili dide lakoko kikà enia, o si fà enia pipọ lẹhin rẹ̀: on pẹlu ṣegbé; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a fọn wọn ká.
Njẹ emi wi fun nyin nisisiyi, Ẹ gafara fun awọn ọkunrin wọnyi, ki ẹ si jọwọ wọn jẹ: nitori bi ìmọ tabi iṣẹ yi ba jẹ ti enia, a o bì i ṣubu:
Ṣugbọn bi ti Ọlọrun ba ni, ẹnyin kì yio le bì i ṣubu; ki o ma ba jẹ pe, a ri nyin ẹ mba Ọlọrun jà.
Nwọn si tẹ̀ si tirẹ̀: nigbati nwọn si pè awọn aposteli wọle, nwọn lù wọn, nwọn si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ li orukọ Jesu mọ́, nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ.
Nitorina nwọn si lọ kuro niwaju ajọ igbimọ: nwọn nyọ̀ nitori ti a kà wọn yẹ si ìya ijẹ nitori orukọ rẹ̀.
Ati li ojojumọ́ ni tẹmpili ati ni ile, nwọn kò dẹkun ikọ́ni, ati lati wasu Jesu Kristi.