Nigbana li ẹnikan de, o wi fun wọn pe, Wo o, awọn ọkunrin ti ẹnyin fi sinu tubu wà ni tẹmpili, nwọn duro nwọn si nkọ́ awọn enia. Nigbana li olori ẹṣọ́ lọ pẹlu awọn onṣẹ, o si mu wọn wá kì iṣe pẹlu ipa: nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn enia, ki a má ba sọ wọn li okuta. Nigbati nwọn si mu wọn de, nwọn mu wọn duro niwaju ajọ igbimọ; olori alufa si bi wọn lẽre, Wipe, Awa kò ti kìlọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yi kọ́ni mọ́? si wo o, ẹnyin ti fi ẹkọ́ nyin kún Jerusalemu, ẹ si npete ati mu ẹ̀jẹ ọkunrin yi wá si ori wa. Ṣugbọn Peteru ati awọn aposteli dahùn, nwọn si wipe, Awa kò gbọdọ má gbọ́ ti Ọlọrun jù ti enia lọ. Ọlọrun awọn baba wa ji Jesu dide, ẹniti ẹnyin pa, tí ẹnyin si gbe kọ́ sori igi. On li Ọlọrun fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ gbéga lati jẹ Ọmọ alade ati Olugbala, lati fi ironupiwada fun Israeli, ati idariji ẹ̀ṣẹ. Awa si li ẹlẹri nkan wọnyi; ati Ẹmí Mimọ́ pẹlu, ti Ọlọrun fifun awọn ti o gbọ́ tirẹ̀. Ṣugbọn nigbati nwọn gbọ́ eyi, àiya wọn gbà ọgbẹ́ de inu, nwọn gbèro ati pa wọn.
Kà Iṣe Apo 5
Feti si Iṣe Apo 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 5:25-33
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò