Iṣe Apo 5:17-26

Iṣe Apo 5:17-26 YBCV

Ṣugbọn olori alufa dide, ti on ti gbogbo awọn ti nwọn wà lọdọ rẹ̀ (ti iṣe ẹya ti awọn Sadusi), nwọn si kún fun owu. Nwọn si nawọ́ mu awọn aposteli, nwọn si fi wọn sinu tubu. Ṣugbọn angẹli Oluwa ṣí ilẹkun tubu li oru; nigbati o si mu wọn jade, o wipe, Ẹ lọ, ẹ duro, ki ẹ si mã sọ gbogbo ọ̀rọ iye yi fun awọn enia ni tẹmpili. Nigbati nwọn si gbọ́ yi, nwọn wọ̀ tẹmpili lọ ni kutukutu, nwọn si nkọ́ni. Ṣugbọn olori alufa de, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, nwọn si pè apejọ igbimọ, ati gbogbo awọn agbàgba awọn ọmọ Israeli, nwọn si ranṣẹ si ile tubu lati mu wọn wá. Ṣugbọn nigbati awọn onṣẹ de ibẹ̀, nwọn kò si ri wọn ninu tubu, nwọn pada wá, nwọn si sọ pe, Awa bá ile tubu o sé pinpin, ati awọn oluṣọ duro lode niwaju ilẹkun: ṣugbọn nigbati awa ṣílẹkun, awa kò bá ẹnikan ninu tubu. Nigbati olori ẹṣọ́ tẹmpili ati awọn olori alufa si gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn dãmu nitori wọn pe, nibo li eyi ó yọri si. Nigbana li ẹnikan de, o wi fun wọn pe, Wo o, awọn ọkunrin ti ẹnyin fi sinu tubu wà ni tẹmpili, nwọn duro nwọn si nkọ́ awọn enia. Nigbana li olori ẹṣọ́ lọ pẹlu awọn onṣẹ, o si mu wọn wá kì iṣe pẹlu ipa: nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn enia, ki a má ba sọ wọn li okuta.