Iṣe Apo 20:1-3

Iṣe Apo 20:1-3 YBCV

NIGBATI ariwo na si rọlẹ, Paulu ranṣẹ pè awọn ọmọ-ẹhin, o si gbà wọn ni iyanju, o dagbere fun wọn, o dide lati lọ si Makedonia. Nigbati o si ti là apa ìha wọnni kọja, ti o si ti fi ọ̀rọ pipọ gbà wọn ni iyanju, o wá si ilẹ Hellene. Nigbati o si duro nibẹ̀ li oṣù mẹta, ti awọn Ju si dèna dè e, bi o ti npete ati ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, o pinnu rẹ̀ lati ba ti Makedonia pada lọ.