ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20:1-3

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20:1-3 YCE

Nígbà tí rògbòdìyàn náà kásẹ̀, Paulu ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì dágbére fún wọn, ó bá lọ sí Masedonia. Bí ó ti ń kọjá ní gbogbo agbègbè náà, bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba àwọn eniyan níyànjú pẹlu ọ̀rọ̀ ìwúrí pupọ títí ó fi dé ilẹ̀ Giriki. Ó ṣe oṣù mẹta níbẹ̀. Bí ó ti fẹ́ máa lọ sí Siria, ó rí i pé àwọn Juu ń dìtẹ̀ sí òun, ó bá gba Masedonia pada.