Nitorina awọn ti o si fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ rẹ̀ a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn. Nwọn si duro ṣinṣin ninu ẹkọ́ awọn aposteli, ati ni idapọ, ni bibu akara ati ninu adura. Ẹ̀rù si ba gbogbo ọkàn: iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi pipọ li a ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe. Gbogbo awọn ti o si gbagbọ́ wà ni ibikan, nwọn ni ohun gbogbo ṣọkan; Nwọn si ntà ohun ini ati ẹrù wọn, nwọn si npín wọn fun olukuluku, gẹgẹ bi ẹnikẹni ti ṣe alaini. Nwọn si nfi ọkàn kan duro li ojojumọ́ ninu tẹmpili ati ni bibu akara ni ile, nwọn nfi inu didùn ati ọkàn kan jẹ onjẹ wọn. Nwọn nyin Ọlọrun, nwọn si ni ojurere lọdọ enia gbogbo. Oluwa si nyàn kún wọn li ojojumọ awọn ti a ngbalà.
Kà Iṣe Apo 2
Feti si Iṣe Apo 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 2:41-47
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò