Iṣe Apo 19:1-7

Iṣe Apo 19:1-7 YBCV

O si ṣe, nigbati Apollo ti wà ni Korinti, ti Paulu kọja lọ niha ẹkùn oke, o wá si Efesu: o si ri awọn ọmọ-ẹhin kan; O wi fun wọn pe, Ẹnyin ha gbà Ẹmí Mimọ́ na nigbati ẹnyin gbagbọ́? Nwọn si wi fun u pe, Awa kò gbọ́ rara bi Ẹmí Mimọ́ kan wà. O si wipe, Njẹ baptismu wo li a ha baptisi nyin si? Nwọn si wipe, Si baptismu ti Johanu. Paulu si wipe, Nitõtọ, ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ̀ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu. Nigbati nwọn si gbọ́, a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa. Nigbati Paulu si gbe ọwọ́ le wọn, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn; nwọn si nfọ̀ ède miran, nwọn si nsọ asọtẹlẹ. Iye awọn ọkunrin na gbogbo to mejila.