O si ṣe, nigbati Apollo ti wà ni Korinti, ti Paulu kọja lọ niha ẹkùn oke, o wá si Efesu: o si ri awọn ọmọ-ẹhin kan;
O wi fun wọn pe, Ẹnyin ha gbà Ẹmí Mimọ́ na nigbati ẹnyin gbagbọ́? Nwọn si wi fun u pe, Awa kò gbọ́ rara bi Ẹmí Mimọ́ kan wà.
O si wipe, Njẹ baptismu wo li a ha baptisi nyin si? Nwọn si wipe, Si baptismu ti Johanu.
Paulu si wipe, Nitõtọ, ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ̀ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu.
Nigbati nwọn si gbọ́, a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa.
Nigbati Paulu si gbe ọwọ́ le wọn, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn; nwọn si nfọ̀ ède miran, nwọn si nsọ asọtẹlẹ.
Iye awọn ọkunrin na gbogbo to mejila.
Nigbati o si wọ̀ inu sinagogu lọ, o fi igboiya sọ̀rọ li oṣù mẹta, o nfi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀, o si nyi wọn lọkan pada si nkan ti iṣe ti ijọba Ọlọrun.
Ṣugbọn nigbati ọkàn awọn miran ninu wọn di lile, ti nwọn kò si gbagbọ́, ti nwọn nsọ̀rọ ibi si Ọna na niwaju ijọ enia, o lọ kuro lọdọ wọn, o si yà awọn ọmọ-ẹhin sọtọ̀, o si nsọ asọye li ojojumọ́ ni ile-iwe Tirannu.
Eyi nlọ bẹ̃ fun iwọn ọdún meji; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti ngbe Asia gbọ́ ọ̀rọ Jesu Oluwa, ati awọn Ju ati awọn Hellene.
Ọlọrun si ti ọwọ́ Paulu ṣe iṣẹ aṣẹ akanṣe,
Tobẹ̃ ti a fi nmu gèle ati ibantẹ́ ara rẹ̀ tọ̀ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn.
Ṣugbọn awọn Ju kan alarinkiri, alẹmi-èṣu-jade, dawọle e li adabọwọ ara wọn, lati pè orukọ Jesu Oluwa si awọn ti o li ẹmi buburu, wipe, Awa fi orukọ Jesu ti Paulu nwasu fi nyin bu.
Awọn meje kan si wà, ọmọ ẹnikan ti a npè ni Skefa, Ju, ati olori kan ninu awọn alufa, ti nwọn ṣe bẹ̃.
Ẹmi buburu na si dahùn, o ni, Jesu emi mọ̀, Paulu emi si mọ̀; ṣugbọn tali ẹnyin?
Nigbati ọkunrin ti ẹmi buburu wà lara rẹ̀ si fò mọ́ wọn, o ba wọn dimú, o bori wọn, bẹ̃ni nwọn sá jade kuro ni ile na ni ìhoho ati ni ifarapa.
Ihìn yi si di mimọ̀ fun gbogbo awọn Ju ati awọn ara Hellene pẹlu ti o ṣe atipo ni Efesu; ẹ̀ru si ba gbogbo wọn, a si gbé orukọ Jesu Oluwa ga.
Ọ̀pọ awọn ti nwọn gbagbọ́ si wá, nwọn jẹwọ, nwọn si fi iṣẹ wọn hàn.
Kì isi ṣe diẹ ninu awọn ti nṣe àlúpàyídà li o kó iwe wọn jọ, nwọn dáná sun wọn loju gbogbo enia: nwọn si ṣírò iye wọn, nwọn si ri i, o jẹ ẹgbã-mẹdọgbọ̀n iwọn fadaka.
Bẹ̃li ọ̀rọ Oluwa si gbilẹ si i gidigidi, o si gbilẹ.