O si wá si Derbe on Listra: si kiyesi i, ọmọ-ẹhin kan wà nibẹ̀, ti a npè ni Timotiu, ọmọ obinrin kan ti iṣe Ju, ti o gbagbọ́; ṣugbọn Hellene ni baba rẹ̀:
Ẹniti a rohin rẹ̀ rere lọdọ awọn arakunrin ti o wà ni Listra ati Ikonioni.
On ni Paulu fẹ ki o ba on lọ; o si mu u, o si kọ ọ ni ilà, nitori awọn Ju ti o wà li àgbegbe wọnni: nitori gbogbo wọn mọ̀ pe, Hellene ni baba rẹ̀.
Bi nwọn si ti nlà awọn ilu lọ, nwọn nfi awọn aṣẹ ti a ti pinnu le wọn lọwọ lati mã pa wọn mọ, lati ọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagbà wá ti o wà ni Jerusalemu.
Bẹ̃ni awọn ijọ si fẹsẹmulẹ ni igbagbọ́, nwọn si npọ̀ si i ni iye lojojumọ.
Nwọn si là ẹkùn Frigia já, ati Galatia, ti a ti ọdọ Ẹmí Mimọ́ kọ̀ fun wọn lati sọ ọ̀rọ na ni Asia.
Nigbati nwọn de ọkankan Misia, nwọn gbé e wò lati lọ si Bitinia: ṣugbọn Ẹmí Jesu kò gbà fun wọn.
Nigbati nwọn si kọja lẹba Misia, nwọn sọkalẹ lọ si Troasi.
Iran kan si hàn si Paulu li oru: ọkunrin kan ara Makedonia duro, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ.
Nigbati o si ti ri iran na, lọgán awa mura lati lọ si Makedonia, a si gbà pe, Oluwa ti pè wa lati wasu ihinrere fun wọn.
Nitorina nigbati awa ṣikọ̀ ni Troasi a ba ọ̀na tàra lọ si Samotrakea, ni ijọ keji a si de Neapoli;
Lati ibẹ̀ awa si lọ si Filippi, ti iṣe ilu Makedonia, olu ilu ìha ibẹ, ilu labẹ Romani: awa si joko ni ilu yi fun ijọ melokan.
Lọjọ isimi, awa si jade lọ si ẹhin odi ilu na, lẹba odò kan, nibiti a rò pe ibi adura wà; awa si joko, a si ba awọn obinrin ti o pejọ sọrọ.
Ati obinrin kan ti orukọ rẹ̀ ijẹ Lidia, elesè àluko, ara ilu Tiatira, ẹniti o nsìn Ọlọrun, o gbọ́ ọ̀rọ wa: ọkàn ẹniti Oluwa ṣí, fetísi ohun ti a ti ẹnu Paulu sọ.
Nigbati a si baptisi rẹ̀, ati awọn ará ile rẹ̀, o bẹ̀ wa, wipe, Bi ẹnyin ba kà mi li olõtọ si Oluwa, ẹ wá si ile mi, ki ẹ si wọ̀ nibẹ̀. O si rọ̀ wa.
O si ṣe, bi awa ti nlọ si ibi adura na, ọmọbinrin kan ti o li ẹmi afọṣẹ, pade wa, ẹniti o fi afọṣẹ mu ère pipọ fun awọn oluwa rẹ̀ wá:
On na li o ntọ̀ Paulu ati awa lẹhin, o si nkigbe, wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹ Ọlọrun Ọgá-ogo, ti nkede ọ̀na igbala fun nyin.
O si nṣe eyi li ọjọ pipọ. Ṣugbọn nigbati inu Paulu bajẹ, ti o si yipada, o wi fun ẹmí na pe, Mo paṣẹ fun ọ li orukọ Jesu Kristi kí o jade kuro lara rẹ̀. O si jade ni wakati kanna.
Nigbati awọn oluwa rẹ̀ si ri pe, igbẹkẹle ère wọn pin, nwọn mu Paulu on Sila, nwọn si wọ́ wọn lọ si ọjà tọ̀ awọn ijoye lọ;
Nigbati nwọn si mu wọn tọ̀ awọn onidajọ lọ, nwọn wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ti iṣe Ju, nwọn nyọ ilu wa lẹnu jọjọ;
Nwọn si nkọni li àṣa ti kò yẹ fun wa, awa ẹniti iṣe ara Romu, lati gbà, ati lati tẹle.