AWỌN woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ati Simeoni ti a npè ni Nigeri, ati Lukiu ara Kirene, ati Manaeni, ti a tọ́ pọ̀ pẹlu Herodu tetrarki, ati Saulu.
Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si.
Nigbati nwọn si ti gbàwẹ, ti nwọn si ti gbadura, ti nwọn si ti gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si rán wọn lọ.
Njẹ bi a ti rán wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ lọ, nwọn sọkalẹ lọ si Seleukia; lati ibẹ̀ nwọn si wọkọ̀ lọ si Kipru.
Nigbati nwọn si wà ni Salami, nwọn nwasu ọ̀rọ Ọlọrun ni sinagogu awọn Ju: nwọn si ni Johanu pẹlu fun iranṣẹ wọn.
Nigbati nwọn si là gbogbo erekùṣu já de Pafo, nwọn ri ọkunrin kan, oṣó, woli eke, Ju, orukọ ẹniti ijẹ Barjesu,
Ẹniti o wà lọdọ Sergiu Paulu bãlẹ ilu na, amoye enia. On na li o ranṣẹ pè Barnaba on Saulu, o si fẹ gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun.
Ṣugbọn Elima oṣó na (nitori bẹ̃ni itumọ̀ orukọ rẹ̀) o takò wọn, o nfẹ pa bãlẹ ni ọkàn da kuro ni igbagbọ́.
Ṣugbọn Saulu (ti a si npè ni Paulu), o kún fun Ẹmí Mimọ́, o si tẹjumọ́ ọ, o si wipe,
Iwọ ti o kún fun arekereke gbogbo, ati fun iwà-ìka gbogbo, iwọ ọmọ Eṣu, iwọ ọta ododo gbogbo, iwọ kì yio ha dẹkun ati ma yi ọna titọ́ Oluwa po?
Njẹ nisisiyi, wo o, ọwọ́ Oluwa mbẹ lara rẹ, iwọ o si fọju, iwọ kì yio ri õrùn ni sã kan. Lojukanna owusuwusu ati òkunkun si bò o; o si nwá enia kiri lati fà a lọwọ lọ.
Nigbati bãlẹ ri ohun ti o ṣe, o gbagbọ́, ẹnu si yà a si ẹkọ́ Oluwa.
Nigbati Paulu ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si ṣikọ̀ ni Pafo, nwọn wá si Perga ni Pamfilia: Johanu si fi wọn silẹ, o si pada lọ si Jerusalemu.
Nigbati nwọn si là Perga kọja, nwọn wá si Antioku ni Pisidia, nwọn si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ isimi, nwọn si joko.
Ati lẹhin kìka iwe ofin ati iwe awọn woli, awọn olori sinagogu ranṣẹ si wọn, pe, Ará, bi ẹnyin ba li ọ̀rọ iyanju kan fun awọn enia, ẹ sọ ọ.
Paulu si dide duro, o si juwọ́ si wọn, o ni, Ẹnyin enia Israeli, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ẹ fi etí silẹ.
Ọlọrun awọn enia Israeli yi, yàn awọn baba wa, o si gbé awọn enia na leke, nigbati nwọn ṣe atipo ni ilẹ Egipti, apá giga li o si fi mu wọn jade kuro ninu rẹ̀.
Ni ìwọn igba ogoji ọdún li o fi mu sũru fun ìwa wọn ni ijù.
Nigbati o si ti run orilẹ-ède meje ni ilẹ Kenaani, o si fi ilẹ wọn fun wọn ni ini fun iwọn ãdọta-le-ni-irinwo ọdun.
Ati lẹhin nkan wọnyi o fi onidajọ fun wọn, titi o fi di igba Samueli woli.
Ati lẹhinna ni nwọn bère ọba: Ọlọrun si fun wọn ni Saulu ọmọ Kiṣi, ọkunrin kan ninu ẹ̀ya Benjamini, fun ogoji ọdún.
Nigbati o si mu u kuro, o gbé Dafidi dide li ọba fun wọn; ẹniti o si jẹri rẹ̀ pe, Mo ri Dafidi ọmọ Jesse ẹni bi ọkàn mi, ti yio ṣe gbogbo ifẹ mi.
Lati inu iru-ọmọ ọkunrin yi ni Ọlọrun ti gbe Jesu Olugbala dide fun Israeli gẹgẹ bi ileri,
Nigbati Johanu ti kọ́ wãsu baptismu ironupiwada fun gbogbo enia Israeli ṣaju wíwa rẹ̀.
Bi Johanu si ti nlà ipa tirẹ̀ já, o ni, Tali ẹnyin ṣebi emi iṣe? Emi kì iṣe on. Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ẹnikan mbọ̀ lẹhin mi, bata ẹsẹ ẹniti emi kò to itú.
Ará, ẹnyin ọmọ iran Abrahamu, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awa li a rán ọ̀rọ igbala yi si.
Nitori awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn olori wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ ọ, ati ọ̀rọ awọn woli, ti a nkà li ọjọjọ isimi, kò yé wọn, nwọn mu u ṣẹ ni didajọ rẹ̀ lẹbi.
Ati bi nwọn kò tilẹ ti ri ọ̀ran iku si i, sibẹ nwọn rọ̀ Pilatu lati pa a.
Bi nwọn si ti mu nkan gbogbo ṣẹ ti a ti kọwe nitori rẹ̀, nwọn si sọ ọ kalẹ kuro lori igi, nwọn si tẹ́ ẹ si ibojì.
Ṣugbọn Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú:
O si farahàn li ọjọ pipọ fun awọn ti o ba a gòke lati Galili wá si Jerusalemu, awọn ti iṣe ẹlẹri rẹ̀ nisisiyi fun awọn enia.
Awa si mu ihinrere wá fun nyin, ti ileri tí a ti ṣe fun awọn baba,
Bi Ọlọrun ti mu eyi na ṣẹ fun awọn ọmọ wa, nigbati o ji Jesu dide; bi a si ti kọwe rẹ̀ ninu Psalmu keji pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ.
Ati niti pe o ji i dide kuro ninu oku, ẹniti kì yio tun pada si ibajẹ mọ́, o wi bayi pe, Emi ó fun nyin ni ore mimọ́ Dafidi, ti o daju.
Nitori o si wi ninu Psalmu miran pẹlu pe, Iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ri idibajẹ.
Nitori lẹhin igba ti Dafidi sin iran rẹ̀ tan bi ifẹ Ọlọrun, o sùn, a si tẹ́ ẹ tì awọn baba rẹ̀, o si ri idibajẹ.
Ṣugbọn ẹniti Ọlọrun ji dide kò ri idibajẹ.
Njẹ ki o yé nyin, ará, pe nipasẹ ọkunrin yi li a nwasu idariji ẹ̀ṣẹ fun nyin:
Ati nipa rẹ̀ li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò le da nyin lare ninu ofin Mose.
Nitorina ẹ kiyesara, ki eyi ti a ti sọ ninu iwe awọn woli ki o maṣe de ba nyin, pe;
Ẹ wo o, ẹnyin ẹlẹgàn, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki a si fẹ nyin kù: nitori emi nṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, iṣẹ ti ẹnyin kò jẹ gbagbọ, bi ẹnikan tilẹ rohìn rẹ̀ fun nyin.
Bi nwọn si ti njade, nwọn bẹ̀bẹ pe ki a sọ̀rọ wọnyi fun wọn li ọjọ isimi ti mbọ̀.
Nigbati nwọn si jade ni sinagogu, ọ̀pọ ninu awọn Ju ati ninu awọn olufọkansìn alawọṣe tẹle Paulu on Barnaba: awọn ẹniti o ba wọn sọ̀rọ ti nwọn si rọ̀ wọn lati duro ninu ore-ọfẹ Ọlọrun.