II. Tim 4:9-18

II. Tim 4:9-18 YBCV

Sa ipa rẹ lati tete tọ̀ mi wá. Nitori Dema ti kọ̀ mi silẹ, nitori o nfẹ aiye isisiyi, o si lọ si Tessalonika; Kreskeni si Galatia, Titu si Dalmatia. Luku nikan li o wà pẹlu mi. Mu Marku wá pẹlu rẹ: nitori o wulo fun mi fun iṣẹ iranṣẹ. Mo rán Tikiku ni iṣẹ lọ si Efesu. Aṣọ otutu ti mo fi silẹ ni Troa lọdọ Karpu, nigbati iwọ ba mbọ̀ mu u wá, ati iwe wọnni, pẹlupẹlu iwe-awọ wọnni. Aleksanderu alagbẹdẹ bàba ṣe mi ni ibi pupọ̀: Oluwa yio san a fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: Lọdọ ẹniti ki iwọ ki o mã ṣọra pẹlu; nitoriti o kọ oju ija si iwasu wa pupọ̀. Li àtetekọ jẹ ẹjọ mi, kò si ẹniti o bá mi gba ẹjọ ro, ṣugbọn gbogbo enia li o kọ̀ mi silẹ: adura mi ni ki a máṣe kà a si wọn li ọrùn. Ṣugbọn Oluwa gbà ẹjọ mi ro, o si fun mi lagbara; pe nipasẹ mi ki a le wãsu na ni awàjálẹ̀, ati pe ki gbogbo awọn Keferi ki o le gbọ́: a si gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì. Oluwa yio yọ mi kuro ninu iṣẹ buburu gbogbo, yio si gbé mi de inu ijọba rẹ̀ ọrun: ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.