II. Tim 1:2-4

II. Tim 1:2-4 YBCV

Si Timotiu, ọmọ mi olufẹ ọwọn: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, ti emi nsìn lati ọdọ awọn baba mi wá ninu ẹri-ọkan funfun, pe li aisimi li emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, T'ọsan t'oru li emi njaìyà ati ri ọ, ti mo nranti omije rẹ, ki a le fi ayọ̀ kún mi li ọkàn