II. Sam 9:1-13

II. Sam 9:1-13 YBCV

DAFIDI si bere pe, ọkan ninu awọn ẹniti iṣe idile Saulu kù sibẹ bi? ki emi ki o le ṣe ore fun u nitori Jonatani. Iranṣẹ kan si ti wà ni idile Saulu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Siba. Nwọn si pè e wá sọdọ Dafidi, ọba si bere lọwọ rẹ̀ pe, Iwọ ni Siba bi? O si dahùn wipe, Iranṣẹ rẹ ni. Ọba si wipe, Kò ha si ọkan ninu idile Saulu sibẹ, ki emi ki o ṣe ore Ọlọrun fun u? Siba si wi fun ọba pe, Jonatani ní ọmọ kan sibẹ ti o ya arọ. Ọba si wi fun u pe, Nibo li o gbe wà? Siba si wi fun ọba pe, Wõ, on wà ni ile Makiri, ọmọ Ammieli, ni Lodebari. Dafidi ọba si ranṣẹ, o si mu u lati ile Makiri ọmọ Ammieli lati Lodebari wá. Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu si tọ̀ Dafidi wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si bu ọla fun u. Dafidi si wipe, Mefiboṣeti. On si dahùn wipe, Wo iranṣẹ rẹ! Dafidi si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: nitoripe nitotọ emi o ṣe ore fun ọ nitori Jonatani baba rẹ, emi o si tun fi gbogbo ilẹ Saulu baba rẹ fun ọ: iwọ o si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi. On si tẹriba, o si wipe, Kini iranṣẹ rẹ jasi, ti iwọ o fi ma wo okú aja bi emi? Ọba si pe Siba iranṣẹ Saulu, o si wi fun u pe, Gbogbo nkan ti iṣe ti Saulu, ati gbogbo eyi ti iṣe ti idile rẹ̀ li emi fi fun ọmọ oluwa rẹ. Iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ ni yio si ma ro ilẹ na fun u, iwọ ni yio si ma mu ikore wá, ọmọ oluwa rẹ yio si ma ri onjẹ jẹ: ṣugbọn Mefiboṣeti ọmọ oluwa rẹ̀ yio si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi. Siba si ni ọmọ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹkunrin. Siba si wi fun ọba pe, Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti pa li aṣẹ fun iranṣẹ rẹ, bẹ̃na ni iranṣẹ rẹ o si ṣe. Ọba si wi pe, Niti Mefiboṣeti, yio ma jẹun ni ibi onjẹ mi, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ọmọ ọba. Mefiboṣeti si ni ọmọ kekere kan, orukọ rẹ̀ njẹ Mika. Gbogbo awọn ti ngbe ni ile Siba li o si nṣe iranṣẹ fun Mefiboṣeti. Mefiboṣeti si ngbe ni Jerusalemu: on a si ma jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ ọba; on si yarọ li ẹsẹ rẹ̀ mejeji.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa