II. Sam 9:1-13

II. Sam 9:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

DAFIDI si bere pe, ọkan ninu awọn ẹniti iṣe idile Saulu kù sibẹ bi? ki emi ki o le ṣe ore fun u nitori Jonatani. Iranṣẹ kan si ti wà ni idile Saulu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Siba. Nwọn si pè e wá sọdọ Dafidi, ọba si bere lọwọ rẹ̀ pe, Iwọ ni Siba bi? O si dahùn wipe, Iranṣẹ rẹ ni. Ọba si wipe, Kò ha si ọkan ninu idile Saulu sibẹ, ki emi ki o ṣe ore Ọlọrun fun u? Siba si wi fun ọba pe, Jonatani ní ọmọ kan sibẹ ti o ya arọ. Ọba si wi fun u pe, Nibo li o gbe wà? Siba si wi fun ọba pe, Wõ, on wà ni ile Makiri, ọmọ Ammieli, ni Lodebari. Dafidi ọba si ranṣẹ, o si mu u lati ile Makiri ọmọ Ammieli lati Lodebari wá. Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu si tọ̀ Dafidi wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si bu ọla fun u. Dafidi si wipe, Mefiboṣeti. On si dahùn wipe, Wo iranṣẹ rẹ! Dafidi si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: nitoripe nitotọ emi o ṣe ore fun ọ nitori Jonatani baba rẹ, emi o si tun fi gbogbo ilẹ Saulu baba rẹ fun ọ: iwọ o si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi. On si tẹriba, o si wipe, Kini iranṣẹ rẹ jasi, ti iwọ o fi ma wo okú aja bi emi? Ọba si pe Siba iranṣẹ Saulu, o si wi fun u pe, Gbogbo nkan ti iṣe ti Saulu, ati gbogbo eyi ti iṣe ti idile rẹ̀ li emi fi fun ọmọ oluwa rẹ. Iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ ni yio si ma ro ilẹ na fun u, iwọ ni yio si ma mu ikore wá, ọmọ oluwa rẹ yio si ma ri onjẹ jẹ: ṣugbọn Mefiboṣeti ọmọ oluwa rẹ̀ yio si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi. Siba si ni ọmọ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹkunrin. Siba si wi fun ọba pe, Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti pa li aṣẹ fun iranṣẹ rẹ, bẹ̃na ni iranṣẹ rẹ o si ṣe. Ọba si wi pe, Niti Mefiboṣeti, yio ma jẹun ni ibi onjẹ mi, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ọmọ ọba. Mefiboṣeti si ni ọmọ kekere kan, orukọ rẹ̀ njẹ Mika. Gbogbo awọn ti ngbe ni ile Siba li o si nṣe iranṣẹ fun Mefiboṣeti. Mefiboṣeti si ngbe ni Jerusalemu: on a si ma jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ ọba; on si yarọ li ẹsẹ rẹ̀ mejeji.

II. Sam 9:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kan, Dafidi bèèrè pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu gbogbo ìdílé Saulu tí mo lè ṣoore fún nítorí Jonatani?” Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Siba, tí ó ti jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Saulu nígbà ayé rẹ̀. Wọ́n pè é wá fún Dafidi, Dafidi sì bi í pé, “Ṣé ìwọ ni Siba?” Siba dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi, èmi ni.” Ọba tún bi í pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu ìdílé Saulu, tí mo lè fi àánú Ọlọrun hàn, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Ọlọrun pé n óo ṣe?” Siba dá a lóhùn pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jonatani wà láàyè, ṣugbọn arọ ni.” Ọba bi í pé, “Níbo ni ó wà?” Siba dá ọba lóhùn pé, “Ó wà ní ilé Makiri, ọmọ Amieli, ní Lodebari.” Dafidi ọba bá ranṣẹ lọ mú un lati ilé Makiri ọmọ Amieli, ní Lodebari. Nígbà tí Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, tíí ṣe ọmọ ọmọ Saulu dé, ó wólẹ̀ níwájú Dafidi, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Dafidi pè é, ó ní, “Mẹfiboṣẹti!” ó sì dá a lóhùn pé, “Èmi, iranṣẹ rẹ nìyí.” Dafidi wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, oore ni mo fẹ́ ṣe ọ́ nítorí Jonatani baba rẹ. Gbogbo ilẹ̀ tí ó ti jẹ́ ti Saulu baba baba rẹ rí, ni n óo dá pada fún ọ, a óo sì jọ máa jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.” Mẹfiboṣẹti tún wólẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó ní, “Kí ni èmi iranṣẹ rẹ fi sàn ju òkú ajá lọ, kí ló dé tí o fi ṣe mí ní oore tí ó tó báyìí?” Ọba bá pe Siba, iranṣẹ Saulu, ó wí fún un pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Saulu, ọ̀gá rẹ tẹ́lẹ̀, ati ti gbogbo ìdílé rẹ̀, ni n óo dá pada fún Mẹfiboṣẹti ọmọ ọmọ rẹ̀. Ìwọ, àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn iranṣẹ rẹ, ni ẹ óo máa ro gbogbo oko Saulu; ẹ ó máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn tí ẹ bá gbìn, kí ọmọ oluwa yín lè ní oúnjẹ tó, ṣugbọn Mẹfiboṣẹti alára, yóo máa wá jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.” Àwọn ọmọkunrin tí Siba ní nígbà náà jẹ́ mẹẹdogun, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì jẹ́ ogún. Siba dáhùn pé, gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni òun yóo ṣe. Mẹfiboṣẹti bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹun lórí tabili ọba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ọba. Ó ní ọdọmọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn ará ilé Siba sì di iranṣẹ Mẹfiboṣẹti. Bẹ́ẹ̀ ni Mẹfiboṣẹti, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji ti rọ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé Jerusalẹmu, ó sì ń jẹun lọ́dọ̀ ọba nígbà gbogbo.

II. Sam 9:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani. Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Saulu, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, Wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ Dafidi, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “ìránṣẹ́ rẹ ni.” Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Saulu síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.” Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Makiri, ọmọ Ammieli, ní Lo-Debari.” Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Makiri ọmọ Ammieli láti Lo-Debari wá. Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu sì tọ Dafidi wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un. Dafidi sì wí pé, “Mefiboṣeti!” Òun sì dáhùn wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!” Dafidi sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù: nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jonatani baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Saulu baba rẹ fún ọ: ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” Mefiboṣeti sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.” Ọba sì pe Ṣiba ìránṣẹ́ Saulu, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Saulu, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ. Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkórè wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí oúnjẹ jẹ: ṣùgbọ́n Mefiboṣeti ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣiba sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.) Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Mefiboṣeti, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.” Mefiboṣeti sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Ṣiba ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Mefiboṣeti. Mefiboṣeti sì ń gbé ní Jerusalẹmu: òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ ọba; òun sì yarọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.