II. Sam 9
9
Dafidi ati Mẹfiboṣẹti
1DAFIDI si bere pe, ọkan ninu awọn ẹniti iṣe idile Saulu kù sibẹ bi? ki emi ki o le ṣe ore fun u nitori Jonatani.
2Iranṣẹ kan si ti wà ni idile Saulu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Siba. Nwọn si pè e wá sọdọ Dafidi, ọba si bere lọwọ rẹ̀ pe, Iwọ ni Siba bi? O si dahùn wipe, Iranṣẹ rẹ ni.
3Ọba si wipe, Kò ha si ọkan ninu idile Saulu sibẹ, ki emi ki o ṣe ore Ọlọrun fun u? Siba si wi fun ọba pe, Jonatani ní ọmọ kan sibẹ ti o ya arọ.
4Ọba si wi fun u pe, Nibo li o gbe wà? Siba si wi fun ọba pe, Wõ, on wà ni ile Makiri, ọmọ Ammieli, ni Lodebari.
5Dafidi ọba si ranṣẹ, o si mu u lati ile Makiri ọmọ Ammieli lati Lodebari wá.
6Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu si tọ̀ Dafidi wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si bu ọla fun u. Dafidi si wipe, Mefiboṣeti. On si dahùn wipe, Wo iranṣẹ rẹ!
7Dafidi si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: nitoripe nitotọ emi o ṣe ore fun ọ nitori Jonatani baba rẹ, emi o si tun fi gbogbo ilẹ Saulu baba rẹ fun ọ: iwọ o si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi.
8On si tẹriba, o si wipe, Kini iranṣẹ rẹ jasi, ti iwọ o fi ma wo okú aja bi emi?
9Ọba si pe Siba iranṣẹ Saulu, o si wi fun u pe, Gbogbo nkan ti iṣe ti Saulu, ati gbogbo eyi ti iṣe ti idile rẹ̀ li emi fi fun ọmọ oluwa rẹ.
10Iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ ni yio si ma ro ilẹ na fun u, iwọ ni yio si ma mu ikore wá, ọmọ oluwa rẹ yio si ma ri onjẹ jẹ: ṣugbọn Mefiboṣeti ọmọ oluwa rẹ̀ yio si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi. Siba si ni ọmọ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹkunrin.
11Siba si wi fun ọba pe, Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti pa li aṣẹ fun iranṣẹ rẹ, bẹ̃na ni iranṣẹ rẹ o si ṣe. Ọba si wi pe, Niti Mefiboṣeti, yio ma jẹun ni ibi onjẹ mi, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ọmọ ọba.
12Mefiboṣeti si ni ọmọ kekere kan, orukọ rẹ̀ njẹ Mika. Gbogbo awọn ti ngbe ni ile Siba li o si nṣe iranṣẹ fun Mefiboṣeti.
13Mefiboṣeti si ngbe ni Jerusalemu: on a si ma jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ ọba; on si yarọ li ẹsẹ rẹ̀ mejeji.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Sam 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.