II. Sam 21
21
Wọ́n pa àwọn Ọmọ Ọmọ Saulu
1IYAN kan si mu ni ọjọ Dafidi li ọdun mẹta, lati ọdun de ọdun; Dafidi si bere lọdọ Oluwa, Oluwa si wipe, Nitori ti Saulu ni, ati nitori ile rẹ̀ ti o kún fun ẹ̀jẹ̀, nitoripe o pa awọn ara Gibeoni.
2Ọba si pe awọn ara Gibeoni, o si ba wọn sọ̀rọ: awọn ara Gibeoni ki iṣe ọkan ninu awọn ọmọ Israeli, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Amori; awọn ọmọ Israeli si ti bura fun wọn: Saulu si nwá ọ̀na ati pa wọn ni itara rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli ati Juda.
3Dafidi si bi awọn ara Gibeoni lere pe, Kili emi o ṣe fun nyin? ati kili emi o fi ṣe etutu, ki ẹnyin ki o le sure fun ilẹ ini Oluwa?
4Awọn ara Gibeoni si wi fun u pe, Awa kò ni fi fadaka tabi wura ti Saulu ati ti idile rẹ̀ ṣe, bẹ̃ni a kò si fẹ ki ẹ pa ẹnikan ni Israeli. O si wipe, eyi ti ẹnyin ba wi li emi o ṣe.
5Nwọn si wi fun ọba pe, ọkunrin ti o run wa, ti o si rò lati pa wa rẹ́ ki a má kù nibikibi ninu gbogbo agbegbe Israeli.
6Mu ọkunrin meje ninu awọn ọmọ rẹ̀ fun wa, awa o si so wọn rọ̀ fun Oluwa ni Gibea ti Saulu ẹniti Oluwa ti yàn. Ọba si wipe, Emi o fi wọn fun nyin.
7Ṣugbọn Ọba dá Mefiboṣeti si, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nitori ibura Oluwa ti o wà larin wọn, lãrin Dafidi ati Jonatani ọmọ Saulu.
8Ọba si mu awọn ọmọkunrin mejeji ti Rispa ọmọbinrin Aia bi fun Saulu, ani Armoni ati Mefiboṣeti: ati awọn ọmọkunrin mararun ti Merabu, ọmọbinrin Saulu, awọn ti o bi fun Adrieli ọmọ Barsillai ara Meholati.
9On si fi wọn le awọn ara Gibea lọwọ, nwọn si so wọn rọ̀ lori oke niwaju Oluwa: awọn mejeje si ṣubu lẹ̃kan, a si pa wọn ni igbà ikore, ni ibẹrẹ ikore ọka-barle.
10Rispa ọmọbinrin Aia si mu aṣọ ọfọ̀ kan, o si tẹ́ ẹ fun ara rẹ̀ lori àpata, ni ibẹrẹ ikore, titi omi fi dà si wọn lara lati ọrun wá, kò si jẹ ki awọn ẹiyẹ oju ọrun bà le wọn li ọsan, tabi awọn ẹranko igbẹ li oru.
11A si rò eyi, ti Rispa ọmọbinrin Aia obinrin Saulu ṣe, fun Dafidi.
12Dafidi si lọ o si ko egungun Saulu, ati egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọkunrin Jabeṣi-gileadi, awọn ti o ti ji wọn kuro ni ita Betṣani, nibiti awọn Filistini gbe so wọn rọ̀, nigbati awọn Filistini pa Saulu ni Gilboa.
13On si mu egungun Saulu ati egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ lati ibẹ na wá; nwọn si ko egungun awọn ti a ti so rọ̀ jọ.
14Nwọn si sin egungun Saulu ati ti Jonatani ọmọ rẹ̀ ni ilẹ Benjamini, ni Sela, ninu iboji Kiṣi baba rẹ̀: nwọn si ṣe gbogbo eyi ti ọba pa li aṣẹ: lẹhin eyini Ọlọrun si gbà ẹbẹ nitori ilẹ na.
Wọ́n Bá Àwọn Òmìrán Filistini Jagun
(I. Kro 20:4-8)
15Ogun si tun wà larin awọn Filistini ati Israeli; Dafidi si sọkalẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si ba awọn Filistini jà: o si rẹ̀ Dafidi.
16Iṣbi-benobu si jẹ ọkan ninu awọn òmirán, ẹniti òṣuwọn ọ̀kọ rẹ̀ jẹ ọdunrun ṣekeli idẹ, on si sán idà titun, o si gbero lati pa Dafidi.
17Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia si ràn a lọwọ, o si kọlu Filistini na, o si pa a. Nigbana ni awọn iranṣẹ Dafidi si bura fun u, pe, Iwọ kì yio si tun ba wa jade lọ si ibi ija mọ, ki iwọ ki o máṣe pa iná Israeli.
18O si ṣe, lẹhin eyi, ija kan si tun wà lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini ni Gobu: nigbana ni Sibbekai ara Huṣa pa Safu, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn òmirán.
19Ija kan si tun wà ni Gobu lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ara Betlehemu si pa arakunrin Goliati ara Gati, ẹniti ọpá ọ̀kọ rẹ̀ dabi idabú igi ti a fi hun aṣọ.
20Ija kan si tun wà ni Gati, ọkunrin kan si wà ti o gùn pupọ, o si ni ika mẹfa li ọwọ́ kan, ati ọmọ-ẹsẹ mẹfa li ẹsẹ kan, apapọ̀ rẹ̀ si jẹ mẹrinlelogun; a si bi on na li òmirán.
21Nigbati on si pe Israeli ni ijà, Jonatani ọmọ Ṣimei arakunrin Dafidi si pa a.
22Awọn mẹrẹrin wọnyi li a bi li òmirán ni Gati, nwọn si ti ọwọ́ Dafidi ṣubu, ati ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Sam 21: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.