II. Sam 12

12
Iṣẹ́ tí Natani Jẹ́ ati Ìrònúpìwàdà Dafidi
1OLUWA si ran Natani si Dafidi. On si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Ọkunrin meji mbẹ ni ilu kan; ọkan jẹ ọlọrọ̀, ekeji si jẹ talaka.
2Ọkunrin ọlọrọ̀ na si ni agutan ati malu li ọ̀pọlọpọ,
3Ṣugbọn ọkunrin talaka na kò si ni nkan, bikoṣe agutan kekere kan, eyi ti o ti rà ti o si ntọ́: o si dagba li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ rẹ̀; a ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀, a si ma mu ninu ago rẹ̀, a si ma dubulẹ li aiya rẹ̀, o si dabi ọmọbinrin kan fun u.
4Alejo kan si tọ̀ ọkunrin ọlọrọ̀ na wá, on kò si fẹ mu ninu agutàn rẹ̀, ati ninu malu rẹ̀, lati fi ṣe alejo fun ẹni ti o tọ̀ ọ wá: o si mu agutan ọkunrin talaka na fi ṣe alejo fun ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá.
5Ibinu Dafidi si fàru gidigidi si ọkunrin na; o si wi fun Natani pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkunrin na ti o ṣe nkan yi, kikú ni yio kú.
6On o si san agutan na pada ni ìlọ́po mẹrin, nitoriti o ṣe nkan yi, ati nitoriti kò ni ãnu.
7Natani si wi fun Dafidi pe, Iwọ li ọkunrin na. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi fi ọ jọba lori Israeli, emi si gbà ọ lọwọ Saulu;
8Emi si fi ile oluwa rẹ fun ọ, ati awọn obinrin oluwa rẹ si aiyà rẹ, emi si fi idile Israeli ati ti Juda fun ọ; iba tilẹ ṣepe eyini kere jù, emi iba si fun ọ ni nkan bayi bayi.
9Eṣe ti iwọ fi kẹgàn ọ̀rọ Oluwa, ti iwọ fi ṣe nkan ti o buru li oju rẹ̀, ani ti iwọ fi fi idà pa Uria ará Hitti, ati ti iwọ fi mu obinrin rẹ̀ lati fi ṣe obinrin rẹ, o si fi idà awọn ọmọ Ammoni pa a.
10Njẹ nitorina idà kì yio kuro ni ile rẹ titi lai; nitoripe iwọ gàn mi, iwọ si mu aya Uria ará Hitti lati fi ṣe aya rẹ.
11Bayi li Oluwa wi, Kiye si i, Emi o jẹ ki ibi ki o dide si ọ lati inu ile rẹ wá, emi o si gbà awọn obinrin rẹ loju rẹ, emi o si fi wọn fun aladugbo rẹ, on o si ba awọn obinrin rẹ sùn niwaju õrun yi.
12Ati pe iwọ ṣe e ni ikọ̀kọ: ṣugbọn emi o ṣe nkan yi niwaju gbogbo Israeli, ati niwaju õrun.
13Dafidi si wi fun Natani pe, Emi ṣẹ̀ si Oluwa. Natani si wi fun Dafidi pe, Oluwa pẹlu si ti mu ẹ̀ṣẹ rẹ kuro; iwọ kì yio kú.
14Ṣugbọn nitori nipa iwa yi, iwọ fi aye silẹ fun awọn ọta Oluwa lati sọ ọ̀rọ òdi, ọmọ na ti a o bi fun ọ, kiku ni yio ku.
15Natani si lọ si ile rẹ̀. Oluwa si fi arùn kọlù ọmọ na ti obinrin Uria bi fun Dafidi, o si ṣe aisàn pupọ.
Ọmọ Dafidi Ṣàìsí
16Dafidi si bẹ̀ Ọlọrun nitori ọmọ na, Dafidi si gbàwẹ, o si wọ inu ile lọ, o si dubulẹ lori ilẹ li oru na.
17Awọn agbà ile rẹ̀ si dide tọ̀ ọ lọ, lati gbe e dide lori ilẹ: o si kọ̀, kò si ba wọn jẹun.
18O si ṣe, ni ijọ keje, ọmọ na si kú. Awọn iranṣẹ Dafidi si bẹ̀ru lati wi fun u pe, ọmọ na kú: nitori ti nwọn wipe, Kiye si i, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, awa sọ̀rọ fun u, on kò si gbọ́ ohùn wa: njẹ yio ti ṣẹ́ ara rẹ̀ ni iṣẹ́ to, bi awa ba wi fun u pe, ọmọ na kú?
19Nigbati Dafidi si ri pe awọn iranṣẹ rẹ̀ nsọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ, Dafidi si kiye si i pe ọmọ na kú: Dafidi si bere lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ọmọ na kú bi? nwọn si da a li ohùn pe, O kú.
20Dafidi si dide ni ilẹ, o si wẹ̀, o fi ororo pa ara, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si wọ inu ile Oluwa lọ, o si wolẹ sìn: o si wá si ile rẹ̀ o si bere, nwọn si gbe onjẹ kalẹ niwaju rẹ̀, o si jẹun.
21Awọn iranṣẹ rẹ̀ si bi li ere pe, Ki li eyi ti iwọ ṣe yi? nitori ọmọ na nigbati o mbẹ lãye iwọ gbawẹ, o si sọkun; ṣugbọn nigbati ọmọ na kú, o dide o si jẹun.
22O si wipe, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, emi gbawẹ, emi si sọkun: nitoriti emi wipe, Tali o mọ̀ bi Ọlọrun o ṣãnu mi, ki ọmọ na ki o le yè.
23Ṣugbọn nisisiyi o ti kú, nitori kili emi o ṣe ma gbawẹ? emi le mu u pada wá mọ bi? emi ni yio tọ̀ ọ lọ, on ki yio si tun tọ̀ mi wá.
Wọ́n Bí Solomoni
24Dafidi si ṣipẹ fun Batṣeba aya rẹ̀, o si wọle tọ̀ ọ, o si ba a dapọ̀: on si bi ọmọkunrin kan, Dafidi si sọ orukọ rẹ̀ ni Solomoni: Oluwa si fẹ ẹ.
25O si rán Natani woli, o si pe orukọ rẹ̀ ni Jedidiah nitori ti Oluwa.
Dafidi Ṣẹgun Raba
(I. Kro 20:1-3)
26Joabu si ba Rabba ti awọn ọmọ Ammoni jagun, o si gbà ilu ọba wọn.
27Joabu si ran awọn iranṣẹ si Dafidi, o si wipe, emi ti ba Rabba jà, emi si ti gbà ilu olomi wọnni.
28Njẹ nitorina kó awọn enia iyokù jọ, ki o si do ti ilu na, ki o si gbà a, ki emi ki o má ba gbà ilu na, ki a ma ba pè e li orukọ mi.
29Dafidi si kó gbogbo enia na jọ, o si lọ si Rabba, o si ba a jà, o si gbà a.
30On si gba adé ọba wọn kuro li ori rẹ̀, wuwo rẹ̀ si jẹ talenti wura kan, o si ni okuta oniyebiye lara rẹ̀: a si fi i de Dafidi li ori. On si kó ikogun ilu na li ọ̀pọlọpọ.
31On si kó awọn enia na ti o wà ninu rẹ̀, o si fi wọn si iṣẹ ayùn, ati si iṣẹ nkan iwọlẹ ti a fi irin ṣe, ati si iṣẹ ãke irin, o si fi wọn si iṣẹ biriki mímọ: bẹ̃na li on si ṣe si gbogbo ilu awọn ọmọ Ammoni. Dafidi ati gbogbo awọn enia na si pada si Jerusalemu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Sam 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa