II. Sam 12:15-23

II. Sam 12:15-23 YBCV

Natani si lọ si ile rẹ̀. Oluwa si fi arùn kọlù ọmọ na ti obinrin Uria bi fun Dafidi, o si ṣe aisàn pupọ. Dafidi si bẹ̀ Ọlọrun nitori ọmọ na, Dafidi si gbàwẹ, o si wọ inu ile lọ, o si dubulẹ lori ilẹ li oru na. Awọn agbà ile rẹ̀ si dide tọ̀ ọ lọ, lati gbe e dide lori ilẹ: o si kọ̀, kò si ba wọn jẹun. O si ṣe, ni ijọ keje, ọmọ na si kú. Awọn iranṣẹ Dafidi si bẹ̀ru lati wi fun u pe, ọmọ na kú: nitori ti nwọn wipe, Kiye si i, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, awa sọ̀rọ fun u, on kò si gbọ́ ohùn wa: njẹ yio ti ṣẹ́ ara rẹ̀ ni iṣẹ́ to, bi awa ba wi fun u pe, ọmọ na kú? Nigbati Dafidi si ri pe awọn iranṣẹ rẹ̀ nsọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ, Dafidi si kiye si i pe ọmọ na kú: Dafidi si bere lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ọmọ na kú bi? nwọn si da a li ohùn pe, O kú. Dafidi si dide ni ilẹ, o si wẹ̀, o fi ororo pa ara, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si wọ inu ile Oluwa lọ, o si wolẹ sìn: o si wá si ile rẹ̀ o si bere, nwọn si gbe onjẹ kalẹ niwaju rẹ̀, o si jẹun. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si bi li ere pe, Ki li eyi ti iwọ ṣe yi? nitori ọmọ na nigbati o mbẹ lãye iwọ gbawẹ, o si sọkun; ṣugbọn nigbati ọmọ na kú, o dide o si jẹun. O si wipe, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, emi gbawẹ, emi si sọkun: nitoriti emi wipe, Tali o mọ̀ bi Ọlọrun o ṣãnu mi, ki ọmọ na ki o le yè. Ṣugbọn nisisiyi o ti kú, nitori kili emi o ṣe ma gbawẹ? emi le mu u pada wá mọ bi? emi ni yio tọ̀ ọ lọ, on ki yio si tun tọ̀ mi wá.