II. Sam 12:1-14

II. Sam 12:1-14 YBCV

OLUWA si ran Natani si Dafidi. On si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Ọkunrin meji mbẹ ni ilu kan; ọkan jẹ ọlọrọ̀, ekeji si jẹ talaka. Ọkunrin ọlọrọ̀ na si ni agutan ati malu li ọ̀pọlọpọ, Ṣugbọn ọkunrin talaka na kò si ni nkan, bikoṣe agutan kekere kan, eyi ti o ti rà ti o si ntọ́: o si dagba li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ rẹ̀; a ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀, a si ma mu ninu ago rẹ̀, a si ma dubulẹ li aiya rẹ̀, o si dabi ọmọbinrin kan fun u. Alejo kan si tọ̀ ọkunrin ọlọrọ̀ na wá, on kò si fẹ mu ninu agutàn rẹ̀, ati ninu malu rẹ̀, lati fi ṣe alejo fun ẹni ti o tọ̀ ọ wá: o si mu agutan ọkunrin talaka na fi ṣe alejo fun ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá. Ibinu Dafidi si fàru gidigidi si ọkunrin na; o si wi fun Natani pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkunrin na ti o ṣe nkan yi, kikú ni yio kú. On o si san agutan na pada ni ìlọ́po mẹrin, nitoriti o ṣe nkan yi, ati nitoriti kò ni ãnu. Natani si wi fun Dafidi pe, Iwọ li ọkunrin na. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi fi ọ jọba lori Israeli, emi si gbà ọ lọwọ Saulu; Emi si fi ile oluwa rẹ fun ọ, ati awọn obinrin oluwa rẹ si aiyà rẹ, emi si fi idile Israeli ati ti Juda fun ọ; iba tilẹ ṣepe eyini kere jù, emi iba si fun ọ ni nkan bayi bayi. Eṣe ti iwọ fi kẹgàn ọ̀rọ Oluwa, ti iwọ fi ṣe nkan ti o buru li oju rẹ̀, ani ti iwọ fi fi idà pa Uria ará Hitti, ati ti iwọ fi mu obinrin rẹ̀ lati fi ṣe obinrin rẹ, o si fi idà awọn ọmọ Ammoni pa a. Njẹ nitorina idà kì yio kuro ni ile rẹ titi lai; nitoripe iwọ gàn mi, iwọ si mu aya Uria ará Hitti lati fi ṣe aya rẹ. Bayi li Oluwa wi, Kiye si i, Emi o jẹ ki ibi ki o dide si ọ lati inu ile rẹ wá, emi o si gbà awọn obinrin rẹ loju rẹ, emi o si fi wọn fun aladugbo rẹ, on o si ba awọn obinrin rẹ sùn niwaju õrun yi. Ati pe iwọ ṣe e ni ikọ̀kọ: ṣugbọn emi o ṣe nkan yi niwaju gbogbo Israeli, ati niwaju õrun. Dafidi si wi fun Natani pe, Emi ṣẹ̀ si Oluwa. Natani si wi fun Dafidi pe, Oluwa pẹlu si ti mu ẹ̀ṣẹ rẹ kuro; iwọ kì yio kú. Ṣugbọn nitori nipa iwa yi, iwọ fi aye silẹ fun awọn ọta Oluwa lati sọ ọ̀rọ òdi, ọmọ na ti a o bi fun ọ, kiku ni yio ku.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú II. Sam 12:1-14

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa