O si ṣe lẹhin ikú Saulu, Dafidi si ti ibi iparun awọn ara Amaleki bọ̀, Dafidi si joko nijọ meji ni Siklagi;
O si ṣe ni ijọ kẹta, si wõ, ọkunrin kan si ti ibudo wá lati ọdọ Saulu; aṣọ rẹ̀ si faya, erupẹ si mbẹ li ori rẹ̀: o si ṣe, nigbati on si de ọdọ Dafidi, o wolẹ, o si tẹriba.
Dafidi si bi i lere pe, Nibo ni iwọ ti wá? o si wi fun u pe, Lati ibudo Israeli li emi ti sa wá.
Dafidi si tun bi lere wipe, Ọràn na ti ri? emi bẹ ọ, sọ fun mi. On si dahun pe, Awọn enia na sa loju ijà, ọ̀pọlọpọ ninu awọn enia na pẹlu si ṣubu; nwọn si kú, Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ si kú pẹlu.
Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o sọ fun u lere pe, Iwọ ti ṣe mọ̀ pe, Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ kú?
Ọmọdekunrin na ti o sọ fun u wipe, Bi emi ti ṣe alabapade lori oke Gilboa, si wõ, Saulu fi ara tì ọkọ̀ rẹ̀, si wõ, kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin nlepa rẹ̀ kikan.
Nigbati o si yi oju wo ẹhin rẹ̀, ti o si ri mi, o pè mi, Emi si da a lohùn pe, Emi nĩ.
On si bi mi pe, Iwọ tani? Emi si da a lohùn pe, ara Amaleki li emi.
On si tun wi fun mi pe, Duro le mi, emi bẹ ọ ki o si pa mi: nitoriti wahala ba mi, ẹmi mi si wà sibẹ.
Emi si duro le e, mo si pa a, nitori ti o da mi loju pe, kò si tun le là mọ lẹhin igbati o ti ṣubu: emi si mu ade ti o wà li ori rẹ̀, ati ibọwọ ti o mbẹ li apa rẹ̀, emi si mu wọn wá ihinyi sọdọ oluwa mi.
Dafidi si di aṣọ rẹ̀ mu, o si fà wọn ya, gbogbo awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀ si ṣe bẹ̃ gẹgẹ.
Nwọn si ṣọfọ, nwọn si sọkun, nwọn si gbawẹ titi di aṣalẹ fun Saulu, ati fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun awọn enia Oluwa, ati fun ile Israeli; nitoripe nwọn ti ipa idà ṣubu.
Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o rò fun u wipe, Nibo ni iwọ ti wá? On si da a li ohùn pe, Ọmọ alejo kan, ara Amaleki li emi iṣe.
Dafidi si wi fun u pe, E ti ri ti iwọ kò fi bẹ̀ru lati nà ọwọ́ rẹ lati fi pa ẹni-àmi-ororo Oluwa?
Dafidi si pe ọkan ninu awọn ọmọdekunrin, o si wipe, Sunmọ ọ, ki o si kọ lu u. O si kọ lu u, on si kú.
Dafidi si wi fun u pe Ẹjẹ rẹ mbẹ li ori ara rẹ; nitoripe ẹnu rẹ li o fi jẹwọ pe, Emi li o pa ẹni-àmi-ororo Oluwa.
Dafidi si fi orin ọ̀fọ yi ṣọ̀fọ̀ lori Saulu ati lori Jonatani ọmọ rẹ̀:
O si pa aṣẹ lati kọ́ awọn ọmọ Juda ni ilò ọrun: wõ, a ti kọ ọ sinu iwe Jaṣeri.
Ẹwà rẹ Israeli li a pa li oke giga rẹ: wò bi awọn alagbara ti ṣubu!
Ẹ máṣe sọ ọ ni Gati, ẹ má si ṣe kokiki rẹ̀ ni igboro Aṣkeloni; ki awọn ọmọbinrin Filistini ki o má ba yọ̀, ki ọmọbinrin awọn alaikọla ki o má ba yọ̀.
Ẹnyin oke Gilboa, ki ìri ki o má si, ati ki ojò ki o má rọ̀ si nyin, ki ẹ má si ni oko ọrẹ ẹbọ: nitori nibẹ li a gbe sọ asà awọn alagbara nu, asà Saulu, bi ẹnipe a ko fi ororo yàn a.
Ọrun Jonatani ki ipada, ati idà Saulu ki ipada lasan lai kan ẹjẹ awọn ti a pa, ati ọra awọn alagbara.
Saulu ati Jonatani ni ifẹni si ara wọn, nwọn si dùn li ọjọ aiye wọn, ati ni ikú wọn, nwọn kò ya ara wọn: nwọn yara ju idì lọ, nwọn si li agbara ju kiniun lọ.
Ẹnyin ọmọbinrin Israeli, ẹ sọkun lori Saulu, ti o fi aṣọ òdodó ati ohun ọṣọ́ wọ̀ nyin, ti o fi ohun ọṣọ́ wura si ara aṣọ nyin.
Wo bi awọn alagbara ti ṣubu larin ogun! A Jonatani! iwọ ti a pa li oke giga rẹ!
Wahala ba mi nitori rẹ, Jonatani, arakunrin mi: didùn jọjọ ni iwọ jẹ fun mi: ifẹ rẹ si mi jasi iyanu, o jù ifẹ obinrin lọ.
Wo bi awọn alagbara ti ṣubu, ati bi ohun ija ti ṣegbe!