II. Pet 2:1-22

II. Pet 2:1-22 YBCV

ṢUGBỌN awọn woli eke wà lãrin awọn enia na pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọ́ni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ́ mu adámọ ègbé wọ̀ inu nyin wá, ani ti yio sẹ́ Oluwa ti o rà wọn, nwọn o si mu iparun ti o yara kánkán wá sori ara wọn. Ọpọlọpọ ni yio si mã tẹle ìwa wọbia wọn; nipa awọn ẹniti a o fi mã sọ ọrọ-odi si ọ̀na otitọ. Ati ninu ojukòkoro ni nwọn o mã fi nyin ṣe ere jẹ nipa ọrọ ẹtàn: idajọ ẹniti kò falẹ̀ lati ọjọ ìwa, ìparun wọn kò si tõgbé. Nitoripe bi Ọlọrun kò ba dá awọn angẹli si ti nwọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apadi, ti o si fi wọn sinu ọgbun òkunkun biribiri awọn ti a pamọ́ de idajọ; Ti kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun; Ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun; O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ: (Nitori ọkunrin olõtọ nì bi o ti ngbe ãrin wọn, ti o nri, ti o si ngbọ́, lojojumọ ni ìwa buburu wọn mba ọkàn otitọ rẹ̀ jẹ́): Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ: Ṣugbọn pãpã awọn ti ntọ̀ ara lẹhin ninu ifẹkufẹ ẽri, ti nwọn si ngàn awọn ijoye, awọn ọ̀yájú, aṣe-tinuẹni, nwọn kò bẹ̀ru ati mã sọ̀rọ ẹgan si awọn oloye. Bẹni awọn angẹli bi nwọn ti pọ̀ ni agbara ati ipá tõ nì, nwọn kò dá wọn lẹjọ ẹ̀gan niwaju Oluwa. Ṣugbọn awọn wọnyi, bi ẹranko igbẹ́ ti kò li ero, ẹranko ṣa ti a dá lati mã mu pa, nwọn nsọ̀rọ ẹgan ninu ọran ti kò yé wọn; a o pa wọn run patapata ninu ibajẹ ara wọn. Nwọn o si jẹ ère aiṣododo, awọn ti nwọn kà a si aiye jijẹ lati mã jẹ adùn aiye li ọsán. Nwọn jẹ́ abawọn ati àbuku, nwọn njaiye ninu asè-ifẹ́ wọn nigbati nwọn ba njẹ ase pẹlu nyin; Awọn oloju ti o kún fun panṣaga, ti kò si le dẹkun ẹ̀ṣẹ idá; ti ntàn awọn ọkàn ti kò fi ẹsẹ mulẹ jẹ: awọn ti nwọn ni ọkàn ti o ti fi ojukòkoro kọ́ra; awọn ọmọ ègún: Nwọn kọ̀ ọ̀na ti o tọ́ silẹ, nwọn si ṣako lọ, nwọn tẹle ọ̀na Balaamu ọmọ Beori, ẹniti o fẹràn ère aiṣododo; Ṣugbọn a ba a wi nitori irekọja rẹ̀: odi kẹtẹkẹtẹ fi ohùn enia sọ̀rọ, o si fi opin si were wolĩ na. Awọn wọnyi ni kanga ti kò li omi, ikũku ti ẹfũfu ngbá kiri; awọn ẹniti a pa òkunkun biribiri mọ́ de tití lai. Nitori igbati nwọn ba nsọ̀rọ ihalẹ asan, ninu ifẹkufẹ ara, nipa wọbia, nwọn a mã tan awọn ti nwọn fẹrẹ má ti ibọ tan kuro lọwọ ti nwọn wà ninu iṣina. Nwọn a mã ṣe ileri omnira fun wọn, nigbati awọn pãpã jẹ ẹrú idibajẹ́: nitori ẹniti o ba ṣẹgun ẹni, on na ni isi sọ ni di ẹrú. Nitori lẹhin ti nwọn ba ti yọ tan kuro ninu ẽri aiye, nipa mimọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi, bi nwọn ba si tun fi ara kó o, ti a si ṣẹgun wọn, igbẹhin wọn a buru jù ti iṣaju lọ. Nitori ìba san fun wọn, ki nwọn ki o má mọ̀ ọ̀na ododo, jù lẹhin ti nwọn mọ̀ ọ tan, ki nwọn ki o yipada kuro ninu ofin mimọ́ ti a fifun wọn. Owe otitọ nì ṣẹ si wọn lara, Ajá tún pada si ẽbì ara rẹ̀; ati ẹlẹdẹ ti a ti wẹ̀ mọ́ sinu àfọ ninu ẹrẹ̀.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú II. Pet 2:1-22