Ọba Assiria si ri ọ̀tẹ ninu Hoṣea: nitoriti o ti rán onṣẹ sọdọ So ọba Egipti, kò si mu ọrẹ fun ọba Assiria wá bi iti mã iṣe li ọdọdun; nitorina ni ọba Assiria há a mọ, o si dè e ni ile tubu.
Nigbana ni ọba Assiria gòke wá si gbogbo ilẹ na, o si gòke lọ si Samaria, o si dotì i li ọdun mẹta.
Li ọdun kẹsan Hoṣea, ni ọba Assiria kó Samaria, o si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori, leti odò Gosani, ati si ilu awọn ara Media.
O si ṣe, nitoriti awọn ọmọ Israeli dẹṣẹ si Oluwa Ọlọrun wọn, ti o ti mu wọn gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro labẹ ọwọ Farao ọba Egipti, ti nwọn si mbẹ̀ru ọlọrun miran.
Ti nwọn si nrìn ninu ilana awọn keferi, ti Oluwa ti le jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, ati ti awọn ọba Israeli, ti nwọn ti ṣe.
Awọn ọmọ Israeli si ṣe ohun ikọ̀kọ ti kò tọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kọ́ ibi giga fun ara wọn ni gbogbo ilu wọn, lati ile-iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.
Nwọn si gbé awọn ere kalẹ, nwọn si dá ere oriṣa si lori òke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo:
Nibẹ ni nwọn si sun turari ni gbogbo ibi giga wọnni, bi awọn keferi ti Oluwa kó lọ niwaju wọn ti ṣe; nwọn si ṣe ohun buburu lati rú ibinu Oluwa soke.
Nitoriti nwọn sìn oriṣa wọnni, eyiti Oluwa ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kò gbọdọ ṣe nkan yi.
Sibẹ Oluwa jẹri si Israeli, ati si Juda, nipa ọwọ gbogbo awọn woli, ati gbogbo awọn ariran, wipe, Ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin, ki ẹ si pa ofin mi ati ilana mi mọ́, gẹgẹ bi gbogbo ofin ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, ti mo rán si nyin nipa ọwọ awọn woli iranṣẹ mi.
Sibẹ nwọn kò fẹ igbọ́, ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, gẹgẹ bi ọrùn awọn baba wọn, ti kò gbà Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́.
Nwọn si kọ̀ ilana rẹ̀, ati majẹmu rẹ̀ silẹ, ti o ba awọn baba wọn dá, ati ẹri rẹ̀ ti o jẹ si wọn: nwọn si ntọ̀ ohun asan lẹhin, nwọn si huwa asan, nwọn si ntọ̀ awọn keferi lẹhin ti o yi wọn ka, niti ẹniti Oluwa ti kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe ṣe bi awọn.
Nwọn si kọ̀ gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, nwọn si ṣe ere didà fun ara wọn, ani, ẹgbọ̀rọ malu meji, nwọn si ṣe ere oriṣa, nwọn si mbọ gbogbo ogun ọrun, nwọn si sìn Baali.
Nwọn si mu ki awọn ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn ki o kọja lãrin iná, nwọn si nfọ̀ afọ̀ṣẹ, nwọn si nṣe alupayida, nwọn si tà ara wọn lati ṣe ibi niwaju Oluwa, lati mu u binu.
Nitorina ni Oluwa ṣe binu si Israeli gidigidi, o si mu wọn kuro niwaju rẹ̀: ọkan kò kù bikòṣe ẹ̀ya Juda nikanṣoṣo.
Juda pẹlu kò pa aṣẹ Oluwa Ọlọrun wọn mọ́, ṣugbọn nwọn rìn ninu ilana Israeli ti nwọn ṣe.
Oluwa si kọ̀ gbogbo iru-ọmọ Israeli silẹ, o si wahala wọn, o si fi wọn le awọn akoni lọwọ, titi o si fi ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀.
Nitori ti o yà Israeli kuro ni idile Dafidi; nwọn si fi Jeroboamu ọmọ Nebati jọba: Jeroboamu si tì Israeli kuro lati má tọ̀ Oluwa lẹhin, o si mu wọn ṣẹ̀ ẹ̀ṣẹ nla.
Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ti o ṣẹ̀; nwọn kò lọ kuro ninu wọn;
Titi Oluwa fi mu Israeli kuro niwaju rẹ̀, bi o ti sọ nipa gbogbo awọn woli iranṣẹ rẹ̀. Bẹ̃li a kó Israeli kuro ni ilẹ wọn lọ si Assiria, titi di oni yi.