II. Joh Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ẹnìkan tí àwọn onigbagbọ àkọ́kọ́ ń pè ní “Alàgbà” ni ó kọ Ìwé Keji Johanu sí arabinrin kan tí ó ṣọ̀wọ́n ati àwọn ọmọ rẹ̀. Bóyá ìjọ kan ati àwọn ọmọ ìjọ yìí ní ìtumọ̀ àdììtú èdè yìí. Kókó ohun tí ó wà ninu ìwé kúkúrú yìí ni ìgbani-níyànjú láti fẹ́ràn ọmọnikeji ẹni ati ìkìlọ̀ nípa àwọn olùkọ́ni èké ati ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ń kọ́ àwọn eniyan.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1-3
Bí ìfẹ́ ṣe tayọ gbogbo nǹǹkan 4-6
Ìkìlọ̀ nípa ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ 7-11
Ọ̀rọ̀ ìparí 12-13
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Joh Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
![None](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2F58%2Fhttps%3A%2F%2Fweb-assets.youversion.com%2Fapp-icons%2Fyo.png&w=128&q=75)
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.