Eyi si ni ifẹ, pe, ki awa ki o mã rìn nipa ofin rẹ̀. Eyi li ofin na, ani bi ẹ ti gbọ́ li àtetekọṣe, pe, ki ẹnyin ki o mã rìn ninu rẹ̀. Nitori ẹlẹtàn pupọ̀ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodisi Kristi. Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà. Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kò si duro ninu ẹkọ́ Kristi, kò gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkọ́, on li o gbà ati Baba ati Ọmọ.
Kà II. Joh 1
Feti si II. Joh 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Joh 1:6-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò