Nitorina ni mo ṣe rò pe o yẹ lati gbà awọn arakunrin niyanju, ki nwọn ki o ṣaju tọ̀ nyin wá, ki nwọn ki o si mura ẹ̀bun nyin silẹ, ti ẹ ti ṣe ileri tẹlẹ ki a le ṣe eyi na silẹ, ki o le jasi bi ohun ẹ̀bun, ki o má si ṣe dabi ti ojukòkoro. Ṣugbọn eyi ni mo wipe, Ẹniti o ba funrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si funrugbin, pupọ, pupọ ni yio ká. Ki olululuku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rẹ̀; kì iṣe àfẹ̀kùnṣe, tabi ti alaigbọdọ má ṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ. Ọlọrun si le mu ki gbogbo ore-ọfẹ ma bisi i fun nyin; ki ẹnyin, ti o ni anito ohun gbogbo nigbagbogbo, le mã pọ̀ si i ni iṣẹ́ rere gbogbo
Kà II. Kor 9
Feti si II. Kor 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 9:5-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò