II. Kor 8:10-15

II. Kor 8:10-15 YBCV

Ati ninu eyi ni mo fi imọran mi fun nyin: nitori eyi ṣanfani fun nyin, ẹnyin ti o kọ́ bẹrẹ niwọn ọdún ti o kọja, kì iṣe lati ṣe nikan, ṣugbọn lati fẹ́ pẹlu. Njẹ nisisiyi ẹ pari ṣiṣe na pẹlu; bi imura-tẹlẹ ati ṣe ti wa, bẹni ki ipari si wa lati inu agbara nyin: Nitori bi imura-tẹlẹ ba wà ṣaju, o jasi itẹwọgbà gẹgẹ bi ohun ti enia bá ni, kì iṣe gẹgẹ bi ohun ti kò ni. Nitori emi kò fẹ ki awọn ẹlomiran wà ni irọrun, ki o si jẹ ipọnju fun nyin, Ṣugbọn nipa idọgba, pe ki ọpọlọpọ ini nyin li akoko yi le ṣe ẹkún aini wọn, ki ọ̀pọlọpọ ini wọn pẹlu le ṣe ẹkún aini nyin: ki idọgba ki o le wà: Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹniti o kó pọ̀ju, kò ni nkan le; ẹniti o si kó kere ju, kò ṣe alainito.