Nitori awa kò si ni tún mã yìn ara wa si nyin mọ́, ṣugbọn awa fi àye fun nyin lati mã ṣogo nitori wa, ki ẹ le ni ohun ti ẹ ó fi da wọn lohùn, awọn ti nṣogo lode ara kì isi iṣe li ọkàn. Nitorina bi ori wa ba bajẹ, fun Ọlọrun ni: tabi bi iye wa ba walẹ̀, fun nyin ni. Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú: O si ti kú fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wà lãye ki o má si ṣe wà lãye fun ara wọn mọ́, bikoṣe fun ẹniti o kú nitori wọn, ti o si ti jinde. Nitorina lati isisiyi lọ awa kò mọ̀ ẹnikan nipa ti ara mọ́; bi awa tilẹ ti mọ̀ Kristi nipa ti ara, ṣugbọn nisisiyi awa kò mọ̀ ọ bẹ̃ mọ́. Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun.
Kà II. Kor 5
Feti si II. Kor 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 5:12-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò