Ọpọlọpọ li o sa nṣogo nipa ti ara, emi ó ṣogo pẹlu.
Nitori ẹnyin fi inu didùn gbà awọn aṣiwère, nigbati ẹnyin tikaranyin jẹ ọlọ́gbọn.
Nitori ẹnyin farada a bi ẹnikan ba sọ nyin di ondè, bi ẹnikan ba jẹ nyin run, bi ẹnikan ba gbà lọwọ nyin, bi ẹnikan ba gbé ara rẹ̀ ga, bi ẹnikan ba gbá nyin loju.
Emi nwi lọna ẹ̀gan, bi ẹnipe awa jẹ alailera. Ṣugbọn ninu ohunkohun ti ẹnikan ni igboiya (emi nsọrọ were), emi ni igboiya pẹlu.
Heberu ni nwọn bi? bẹ̃li emi. Israeli ni nwọn bi? bẹ̃li emi. Irú ọmọ Abrahamu ni nwọn bi? bẹ̃li emi.
Iranṣẹ Kristi ni nwọn bi? (emi nsọ bi aṣiwère) mo ta wọn yọ; niti lãlã lọpọlọpọ, niti paṣan mo rekọja, niti tubu nigbakugba, niti ikú nigbapupọ.
Nigba marun ni mo gbà paṣan ogoji dín kan lọwọ awọn Ju.
Nigba mẹta li a fi ọgọ lù mi, ẹkanṣoṣo li a sọ mi li okuta, ẹ̃mẹta li ọkọ̀ rì mi, ọsán kan ati oru kan ni mo wà ninu ibú.
Ni ìrin àjò nigbakugba, ninu ewu omi, ninu ewu awọn ọlọṣa, ninu ewu awọn ara ilu mi, ninu ewu awọn keferi, ninu ewu ni ilu, ninu ewu li aginjù, ninu ewu loju okun, ninu ewu larin awọn eke arakunrin;
Ninu lãlã ati irora, ninu iṣọra nigbakugba, ninu ebi ati orùngbẹ, ninu àwẹ nigbakugba, ninu otutù ati ìhoho.
Pẹlu nkan wọnni ti o wà lode, eyi ti nwọjọ tì mi li ojojumọ́, emi ko yé ṣe aniyan gbogbo ijọ.
Tani iṣe alailera, ti emi kò ṣe alailera? tabi tali a mu kọsẹ̀, ti ara mi kò gbina?
Bi emi kò le ṣaima ṣogo, emi o kuku mã ṣogo nipa awọn nkan ti iṣe ti ailera mi.
Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu Kristi, ẹniti iṣe olubukún julọ lailai, mọ̀ pe emi kò ṣeke.
Ni Damasku, bãlẹ ti o wà labẹ ọba Areta fi ẹgbẹ ogun ká ilu awọn ara Damasku mọ́, o nfẹ mi lati mu:
Ati loju ferese ninu agbọ̀n li a si ti sọ̀ mi kalẹ lẹhin odi, ti mo si bọ́ lọwọ rẹ̀.