II. Kor 10:2-5

II. Kor 10:2-5 YBCV

Ṣugbọn emi bẹ̀ nyin pe ki o máṣe nigbati mo wà larin nyin ni mo fi igboiya han pẹlu igbẹkẹle ti mo rò pe mo ni igboiya si awọn kan, ti nrò wa si bi ẹniti nrin nipa ti ara. Nitoripe bi awa tilẹ nrìn ni ti ara, ṣugbọn awa kò jagun nipa ti ara: (Nitori ohun ija wa kì iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ;) Awa nsọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rẹ̀ ga si ìmọ Ọlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi