Olubukún li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọ́nu, ati Ọlọrun itunu gbogbo; Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahalà wa, nipa itunu na ti a fi ntù awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o le mã tù awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu. Nitoripe bi ìya Kristi ti di pipọ ninu wa, gẹgẹ bẹ̃ni itunu wa di pipọ pẹlu nipa Kristi. Ṣugbọn bi a ba si npọ́n wa loju ni, o jasi bi itunu ati igbala nyin, ti nṣiṣẹ ni ifàiyarán awọn iya kannã ti awa pẹlu njẹ: tabi bi a ba ntù wa ninu, o jasi fun itunu ati igbala nyin.
Kà II. Kor 1
Feti si II. Kor 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 1:3-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò