II. Kro 9
9
Ìbẹ̀wò Ọbabinrin Ṣeba sí Solomoni
(I. A. Ọba 10:1-13)
1NIGBATI ayaba Ṣeba gbọ́ òkiki Solomoni, o wá lati fi àlọ dan Solomoni wò ni Jerusalemu, pẹlu ẹgbẹ́ nlanla, ati ibakasiẹ ti o ru turari, ati wura li ọ̀pọlọpọ ati okuta iyebiye; nigbati o si de ọdọ Solomoni, o ba a sọ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.
2Solomoni si dahùn gbogbo ibère rẹ̀: kò si si ohun kan ti o pamọ fun Solomoni ti kò sọ fun u,
3Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́,
4Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati aṣọ-wiwọ̀ wọn; ati awọn agbọti rẹ̀ pẹlu aṣọ-wiwọ̀ wọn, ati àtẹgun ti o mba gòke lọ si ile Oluwa; kò si kù agbara kan ninu rẹ̀ mọ.
5O si wi fun ọba pe, otitọ ni ọ̀rọ ti mo gbọ́ ni ilẹ mi niti iṣe rẹ, ati ọgbọ́n rẹ:
6Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ wọn gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri i; si kiyesi i, a kò rò idaji titobi ọgbọ́n rẹ fun mi; nitori ti iwọ kọja òkiki ti mo ti gbọ́.
7Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún si ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro nigbagbogbo niwaju rẹ, ti o si ngbọ́ ọgbọ́n rẹ.
8Olubukún li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o fẹran rẹ lati gbé ọ ka ori itẹ́ rẹ̀ lati ṣe ọba fun Oluwa Ọlọrun rẹ: nitoriti Ọlọrun rẹ fẹran Israeli lati fi idi wọn kalẹ lailai, nitorina ni o ṣe fi ọ jọba lori wọn, lati ṣe idajọ ati otitọ.
9O si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọpọlọpọ, ati okuta iyebiye: bẹ̃ni kò ti isi iru turari gẹgẹ bi eyiti ayaba Ṣeba fun Solomoni ọba.
10Awọn iranṣẹ Huramu pẹlu, ati awọn iranṣẹ Solomoni ti o mu wura Ofiri wá, si mu igi-algumu, ati okuta iyebiye wá pẹlu.
11Ọba si fi igi-algumu na ṣe àtẹgun ni ile Oluwa, ati ni ile ọba, ati duru ati ohun ọ̀na-orin fun awọn akọrin: a kò si ri iru bẹ̃ ri ni ilẹ Juda.
12Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba li ohun gbogbo ti o wù u, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti o mu wa fun ọba. Bẹ̃ni o yipada, o si lọ si ilẹ rẹ̀, ati on ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
Ọrọ̀ Solomoni Ọba
(I. A. Ọba 10:14-25)
13Njẹ nisisiyi ìwọn wura ti o de fun Solomoni li ọdun kan ni ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura.
14Laika eyiti awọn oniṣowo ati awọn èro mu wá. Ati awọn ọba Arabia, ati awọn bãlẹ ilẹ na nmu wura ati fadakà tọ̀ Solomoni wá.
15Solomoni ọba si ṣe igba asà wura lilù: asà kan gba ẹgbẹta ṣekeli wura lilù.
16Ọdunrun apata wura lilù li o si ṣe; apata kan gbà ọ̃dunrun ṣekeli wura: ọba si fi wọn sinu ile igbo Lebanoni.
17Ọba si ṣe itẹ́ ehin-erin nla kan, o si fi wura daradara bò o.
18Àtẹgun mẹfa ni itẹ́ na ni, pẹlu apoti-itisẹ wura kan, ti a dè mọ itẹ́ na, ati irọpa ni iha mejeji ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba awọn irọpa na.
19Kiniun mejila si duro lori atẹgun mẹfẹfa na, ni iha ekini ati ni iha ekeji. A kò ṣe iru rẹ̀ ri ni gbogbo ijọba.
20Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni, wura daradara ni: kò si ti fadakà; a kò kà fadakà si nkankan li ọjọ Solomoni.
21Nitori awọn ọkọ̀ ọba nlọ si Tarṣiṣi pẹlu awọn iranṣẹ Huramu; ẹ̃kan li ọdun mẹta li awọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ide, nwọn nmu wura, ati fadakà, ati ehin-erin, ati inaki, ati ẹiyẹ-ologe wá.
22Solomoni ọba si tobi jù gbogbo ọba aiye lọ li ọrọ̀ ati li ọgbọn.
23Gbogbo awọn ọba aiye si nwá oju Solomoni, lati gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀ ti Ọlọrun ti fi si i li ọkàn.
24Olukuluku si mu ọrẹ tirẹ̀ wá, ohun-elo fadakà ati ohun-elo wura, ati aṣọ ibora, ihamọra, ati turari, ẹṣin, ati ibaka, iye kan li ọdọdun.
25Solomoni si ni ẹgbaji ile fun ẹṣin ati kẹkẹ́, ati ẹgbafa ẹlẹṣin, ti o fi si awọn ilu kẹkẹ́, ati ọdọ ọba ni Jerusalemu.
26O si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò (Euferate) titi de ilẹ awọn ara Filistia ati de àgbegbe Egipti.
27Ọba si sọ fadakà dabi okuta ni Jerusalemu, ati igi-kedari li o si ṣe bi sikamore, ti o wà ni pẹtẹlẹ li ọ̀pọlọpọ.
28Nwon si mu ẹṣin tọ̀ Solomoni lati Egipti wá, ati lati ilẹ gbogbo.
Ìjọba Solomoni Ní Ṣókí
(I. A. Ọba 11:41-43)
29Ati iyokù iṣe Solomoni ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kọ ha kọ wọn sinu iwe Natani woli, ati sinu asọtẹlẹ Ahijah, ara Ṣilo, ati sinu iran Iddo, ariran, sipa Jeroboamu, ọmọ Nebati.
30Solomoni si jọba ni Jerusalemu lori gbogbo Israeli li ogoji ọdun.
31Solomoni si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi baba rẹ̀: Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.