II. Kro 36:17-23

II. Kro 36:17-23 YBCV

Nitorina li o ṣe mu ọba awọn ara Kaldea wá ba wọn, ẹniti o fi idà pa awọn ọdọmọkunrin wọn ni ile ibi-mimọ́ wọn, kò si ni iyọ́nu si ọdọmọkunrin tabi wundia, arugbo, tabi ẹniti o bà fun ogbó: on fi gbogbo wọn le e li ọwọ. Ati gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun, nla ati kekere, ati iṣura ile Oluwa ati iṣura ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; gbogbo wọn li o mu wá si Babeli. Nwọn si kun ile Ọlọrun, nwọn si wó odi Jerusalemu palẹ, nwọn si fi iná sun ãfin rẹ̀, nwọn si fọ́ gbogbo ohun-elo daradara rẹ̀ tũtu. Awọn ti o ṣikù lọwọ idà li o kó lọ si Babeli; nibiti nwọn jẹ́ iranṣẹ fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ titi di ijọba awọn ara Persia: Lati mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wá, titi ilẹ na yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi ãdọrin ọdun yio fi pé. Li ọdun kini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ Oluwa lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, Oluwa ru ẹmi Kirusi, ọba Persia, soke, ti o si ṣe ikede ni gbogbo ijọba rẹ̀, o si kọ iwe pẹlu, wipe, Bayi ni Kirusi, ọba Persia, wi pe, Gbogbo ijọba aiye li Oluwa Ọlọrun fi fun mi, o si ti paṣẹ fun mi lati kọ́ ile kan fun on ni Jerusalemu, ti mbẹ ni Juda. Tani ninu nyin ninu gbogbo awọn enia rẹ̀? Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ki o pẹlu rẹ̀, ki o si gòke lọ.