II. Kro 27
27
Jotamu, Ọba Juda
(II. A. Ọba 15:32-38)
1ẸNI ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jotamu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jeruṣa, ọmọbinrin Sadoku.
2O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe; kiki kò wọ inu tempili Oluwa lọ, ṣugbọn awọn enia nṣe ibi sibẹsibẹ.
3On si kọ́ ẹnu-ọ̀na giga ile Oluwa, ati lori odi Ofeli, o kọ́ pupọ.
4Ani o kọ́ ilu wọnni li òke Juda, ati ninu igbo, o mọ ile-odi ati ile-iṣọ.
5O si ba ọba awọn ara Ammoni jà pẹlu, o si bori wọn. Awọn ara Ammoni si fun u li ọgọrun talenti fadakà li ọdun na, ati ẹgbãrun oṣuwọn alikama, ati ẹgbãrun ti barli. Eyi li awọn ara Ammoni san fun u, ati lọdun keji ati lọdun kẹta.
6Bẹ̃ni Jotamu di alagbara, nitoriti o tun ọ̀na rẹ̀ ṣe niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.
7Ati iyokù iṣe Jotamu ati gbogbo ogun rẹ̀, ati ọ̀na rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda.
8Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu.
9Jotamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Ahasi, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 27: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.