II. Kro 18
18
Wolii Mikaya Kìlọ̀ fún Ahabu
(I. A. Ọba 22:1-28)
1JEHOṢAFATI si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ, o si ba Ahabu dá ana.
2Lẹhin ọdun melokan, on sọ̀kalẹ tọ Ahabu lọ si Samaria. Ahabu si pa agutan ati malu fun u li ọ̀pọlọpọ ati fun awọn enia ti o pẹlu rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati ba a gòke lọ si Ramoti-Gileadi.
3Ahabu ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati ọba Juda pe, Iwọ o ha ba mi lọ si Ramoti-Gileadi bi? On si da a li ohùn wipe, Emi bi iwọ, ati enia mi bi enia rẹ; awa o pẹlu rẹ li ogun na.
4Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa loni.
5Nitorina ọba Israeli kó awọn woli jọ, irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki awa ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Gòke lọ; Ọlọrun yio si fi i le ọba lọwọ.
6Ṣugbọn Jehoṣafati wipe, kò si woli Oluwa nihin pẹlu, ti awa ìba bère lọwọ rẹ̀?
7Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan mbẹ sibẹ lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀: nitoriti kò jẹ sọ asọtẹlẹ rere si mi lai, bikòṣe ibi nigbagbogbo: eyini ni Mikaiah, ọmọ Imla. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba ki o má sọ bẹ̃.
8Ọba Israeli si pè ìwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah ọmọ Imla, ki o yara wá.
9Ati ọba Israeli, ati Jehoṣafati, ọba Juda joko, olukuluku lori itẹ rẹ̀, nwọn si wọ aṣọ igunwa wọn, nwọn si joko ni ita ẹnubọde Samaria; gbogbo awọn woli si nsọ asọtẹlẹ niwaju wọn.
10Sedekiah ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn awọn ara Siria titi iwọ o fi run wọn.
11Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe, Gòke lọ si Ramoti-Gileadi, iwọ o ṣe rere; Oluwa yio si fi i le ọba lọwọ.
12Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah si wi fun u pe, Kiye si i, awọn woli fi ẹnu kan sọ rere fun ọba: Njẹ emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọkan ninu ti wọn, ki o si sọ rere.
13Mikaiah si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ani, eyiti Ọlọrun mi ba wi li emi o sọ.
14Nigbati o si tọ̀ ọba wá, ọba sọ fun u pe, Mikaiah, ki awa ki o lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? O si wipe, Ẹ lọ, ẹnyin o si ṣe rere, a o si fi wọn le nyin lọwọ.
15Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bú ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikòṣe ọ̀rọ otitọ li orukọ Oluwa?
16On si wipe, Emi ri gbogbo Israeli fọnka kiri lori awọn òke, bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa: jẹ ki nwọn ki o pada, olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.
17Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò ti wi fun ọ pe: on kì isọtẹlẹ rere si mi, bikòṣe ibi?
18Mikaiah si wipe, Nitorina, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun ọrun duro lapa ọtún ati lapa òsi rẹ̀.
19Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ọba Israeli, ki o le gòke lọ ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ekini si sọ bayi, ekeji si sọ miran.
20Nigbana ni ẹmi na jade wá, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Emi o tàn a. Oluwa si wi fun u pe, Bawo?
21On si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. Oluwa si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃ na.
22Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ.
23Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana, sunmọ ọ, o si lù Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà kọja lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ.
24Mikaiah si wipe, Kiyesi i, iwọ o ri i li ọjọ na, nigbati iwọ o wọ inu iyẹwu de inu iyẹwu lọ ifi ara rẹ pamọ́,
25Nigbana ni ọba Israeli wipe, Ẹ mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba.
26Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi, ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi ọnjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia.
27Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ọdọ mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo!
Ikú Ahabu
(I. A. Ọba 22:29-35)
28Bẹ̃li ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, si gòke lọ si Ramoti-Gileadi.
29Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ìja; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Bẹ̃li ọba Israeli si pa aṣọ dà: nwọn si lọ si oju ìja.
30Ṣugbọn ọba Siria ti paṣẹ fun awọn olori kẹkẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀, pe, Ẹ máṣe ba ewe tabi àgba jà, bikòṣe ọba Israeli nikan.
31O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ ri Jehoṣafati, ni nwọn wipe eyi li ọba Israeli, nitorina nwọn yi i ka lati ba a jà: ṣugbọn Jehoṣafati kigbe, Oluwa si ràn a lọwọ: Ọlọrun si yi wọn pada kuro lọdọ rẹ̀.
32O si ṣe, bi awọn olori kẹkẹ́ ti woye pe kì iṣe ọba Israeli, nwọn yipada kuro lẹhin rẹ̀.
33Ọkunrin kan si fa ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin, o si wi fun olutọju kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ rẹ pada, ki o mu mi jade kuro loju ìja; nitoriti mo gbọgbẹ́.
34Ija na si pọ̀ li ọjọ na: pẹlupẹlu ọba Israeli duro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ kọju si awọn ara Siria titi di aṣãlẹ: o si kú li akokò ìwọ õrun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 18: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.