II. Kro 17:3-5

II. Kro 17:3-5 YBCV

Oluwa si wà pẹlu Jehoṣafati, nitoriti o rìn ninu ọ̀na iṣaju Dafidi, baba rẹ̀, kò si wá Baalimu: Ṣugbọn o wá Ọlọrun baba rẹ̀, o si rìn ninu ofin rẹ̀, ki iṣe bi iṣe Israeli. Nitorina ni Oluwa fi idi ijọba na mulẹ li ọwọ rẹ̀; gbogbo Juda si ta Jehoṣafati li ọrẹ, on si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ.