II. Kro 17
17
Jehoṣafati di Ọba
1JEHOṢAFATI, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀, o si mu ara rẹ̀ le si Israeli.
2O si fi ogun sinu gbogbo ilu olodi Juda, o si fi ẹgbẹ-ogun si ilẹ Juda ati sinu ilu Efraimu wọnni, ti Asa baba rẹ̀ ti gbà.
3Oluwa si wà pẹlu Jehoṣafati, nitoriti o rìn ninu ọ̀na iṣaju Dafidi, baba rẹ̀, kò si wá Baalimu:
4Ṣugbọn o wá Ọlọrun baba rẹ̀, o si rìn ninu ofin rẹ̀, ki iṣe bi iṣe Israeli.
5Nitorina ni Oluwa fi idi ijọba na mulẹ li ọwọ rẹ̀; gbogbo Juda si ta Jehoṣafati li ọrẹ, on si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ.
6Ọkàn rẹ̀ si gbé soke li ọ̀na Oluwa: pẹlupẹlu o si mu ibi giga wọnni ati ere-oriṣa kuro ni Juda.
7Ati li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o ranṣẹ si awọn ijoye rẹ̀, ani si Benhaili ati si Obadiah ati Sekariah, ati si Netaneeli, ati si Mikaiah, lati ma kọ́ni ninu ilu Juda wọnni.
8Ati pẹlu wọn, o rán awọn ọmọ Lefi, ani Ṣemaiah, ati Netaniah, ati Sebadiah, ati Asaheli, ati Ṣemiramotu, ati Jehonatani, ati Adonijah, ati Tobijah, ati Tob-Adonijah, awọn ọmọ Lefi; ati pẹlu wọn Eliṣama, ati Jehoramu, awọn alufa.
9Nwọn si kọ́ni ni Juda, nwọn si ni ofin Oluwa pẹlu wọn, nwọn si lọ kakiri ja gbogbo ilu Juda, nwọn si kọ́ awọn enia.
Títóbi Jehoṣafati
10Ẹ̀ru Oluwa si ba gbogbo ijọba ilẹ na, ti o wà yikakiri Juda, tobẹ̃ ti nwọn kò ba Jehoṣafati jagun kan.
11Ati ninu awọn ara Filistia mu ọrẹ fun Jehoṣafati wá, ati fadakà owo ọba: awọn ara Arabia si mu ọwọ́-ẹran fun u wá, ẹgbãrin àgbo o di ọ̃dunrun, ati ẹgbãrin obukọ di ọ̃dunrun.
12Jehoṣafati si npọ̀ si i gidigidi: o si kọ́ ile olodi, ati ilu iṣura ni Juda.
13O si ni iṣura pupọ ni ilu Juda; ati awọn jagunjagun, awọn alagbara akọni ọkunrin ti o wà ni Jerusalemu.
14Wọnyi ni iye wọn gẹgẹ bi ile baba wọn: Ninu Juda, awọn olori ẹgbẹgbẹrun; Adna, olori, ati pẹlu rẹ̀, ọkẹ́ mẹ̃dogun alagbara akọni ọkunrin.
15Ati atẹle rẹ̀ ni Jehohanani olori, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹrinla ọkunrin.
16Ati atẹle rẹ̀ ni Amasiah, ọmọ Sikri, ti o fi tinutinu fi ara rẹ̀ fun Oluwa; ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹwa alagbara akọni ọkunrin.
17Ati ninu Benjamini; Eliada alagbara akọni ọkunrin, ati pẹlu rẹ̀ awọn enia ti nfi ọrun ati apata hamọra, ọkẹ mẹwa.
18Ati atẹle rẹ̀ ni Jehosabadi, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹsan, ti o mura silẹ de ogun.
19Wọnyi nduro tì ọba, li aika awọn ti ọba fi sinu ilu olodi ni gbogbo Juda.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 17: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.