II. Kro 11
11
Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣemaaya
(I. A. Ọba 12:21-24)
1NIGBATI Rehoboamu si de Jerusalemu o kó ile Juda ati Benjamini jọ, ọkẹ mẹsan enia ti a yàn, ti nwọn iṣe ologun, lati ba Israeli jà, ki o le mu ijọba na pada bọ̀ sọdọ Rehoboamu.
2Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ Ṣemaiah, enia Ọlọrun, wá, wipe,
3Sọ fun Rehoboamu ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati fun gbogbo Israeli ni Juda ati Benjamini, wipe,
4Bayi li Oluwa wi, ẹnyin kò gbọdọ gòke lọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ki olukuluku pada si ile rẹ̀: nitori ọ̀ran yi lati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbà ọ̀rọ Oluwa gbọ́, nwọn si yipada kuro lati lọ iba Jeroboamu.
Rehoboamu Mọ Odi yí Àwọn Ìlú Ká
5Rehoboamu si ngbe Jerusalemu, o si kọ́ ilu olodi ni Juda.
6O kọ́ Betlehemu pẹlu, ati Etamu, ati Tekoa,
7Ati Bet-Suri, ati Soko, ati Adullamu,
8Ati Gati, ati Mareṣa, ati Sifu,
9Ati Adoraimu, ati Lakiṣi, ati Aseki,
10Ati Sora, ati Aijaloni, ati Hebroni, ti o wà ni Juda ati ni Benjamini, awọn ilu olodi.
11O si mu awọn ilu olodi lagbara, o si fi awọn balogun sinu wọn ati akojọ onjẹ, ati ororo ati ọti-waini.
12Ati ni olukuluku ilu li o fi asà ati ọ̀kọ si, o si mu wọn lagbara gidigidi, o si ni Juda ati Benjamini labẹ rẹ̀.
13Ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ti o wà ni gbogbo Israeli, tọ̀ ọ lọ lati gbogbo ibugbe wọn wá.
14Nitori ti awọn ọmọ Lefi fi ìgberiko wọn silẹ, ati ini wọn, nwọn si lọ si Juda ati Jerusalemu: nitori Jeroboamu ati awọn ọmọ rẹ̀ ti le wọn kuro lati ma ṣiṣẹ alufa fun Oluwa.
15O si yàn awọn alufa fun ibi-giga wọnni, ati fun awọn ere-obukọ ati fun ẹ̀gbọrọ-malu ti o ti ṣe.
16Lẹhin wọn iru awọn ti o fi ọkàn wọn si ati wá Oluwa Ọlọrun Israeli lati inu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli wá, si wá si Jerusalemu, lati ṣe irubọ si Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn.
17Bẹ̃ni nwọn si mu ijọba Juda lagbara, nwọn mu ki Rehoboamu, ọmọ Solomoni ki o lagbara li ọdun mẹta: nitori li ọdun mẹta ni nwọn rìn li ọ̀na Dafidi ati Solomoni.
Àwọn Ìdílé Rehoboamu
18Rehoboamu si mu Mahalati, ọmọbinrin Jerimoti, ọmọ Dafidi, li aya, ati Abihaili, ọmọbinrin Eliabi, ọmọ Jesse:
19Ẹniti o bi ọmọkunrin wọnyi fun u; Jeuṣi, ati Ṣamariah, ati Sahamu.
20Ati lẹhin rẹ̀, o mu Maaka, ọmọbinrin Absalomu ti o bi Abijah fun u, ati Attai, ati Sisa, ati Ṣelomiti.
21Rehoboamu si fẹran Maaka ọmọbinrin Absalomu, jù gbogbo awọn aya rẹ̀ ati àle rẹ̀ lọ: (nitoriti o ni aya mejidilogun, ati ọgọta àle: o si bi ọmọkunrin mejidilọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin).
22Rehoboamu si ṣe Abijah, ọmọ Maaka, li olori lati ṣe olori ninu awọn arakunrin rẹ̀: nitori ti o rò lati fi i jọba.
23On si huwà ọlọgbọ́n, o si tú ninu gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ka si gbogbo ilẹ Juda ati Benjamini, si olukuluku ilu olodi: o si fun wọn li onjẹ li ọ̀pọlọpọ. O si fẹran ọ̀pọlọpọ obinrin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 11: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.