I. Tes Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Tẹsalonika ni olú-ìlú ìpínlẹ̀ Masedonia tí ó wà ní abẹ́ ìjọba Romu. Paulu dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀ lẹ́yìn tí ó kúrò ní Filipi. Ṣugbọn kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà tí àwọn Juu kan fi bẹ̀rẹ̀ sí tako Paulu, nítorí pé wọ́n ń jowú rẹ̀ pé ó ṣe àṣeyege; nítorí pé ó waasu nípa ẹ̀sìn igbagbọ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu, ṣugbọn tí wọ́n ní ìfẹ́ sí ẹ̀sìn àwọn Juu. Túlààsì ni Paulu fi kúrò ní Tẹsalonika tí ó sì lọ sí Beria. Nígbà tí ó yá, tí ó dé Kọrinti, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ kan tí ń jẹ́ Timotiu fún un ní ìròyìn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní Tẹsalonika.
Ní àkókò yìí ni Paulu kọ ìwé rẹ̀ kinni sí àwọn ará Tẹsalonika. Ó kọ ọ́ láti mú àwọn onigbagbọ tí wọ́n wà níbẹ̀ lọ́kàn le ati láti fún wọn ní ìdánilójú. Ó dúpẹ́ fún ìròyìn tí ó gbọ́ nípa ìfẹ́ ati igbagbọ wọn, ó sì rán wọn létí irú ìgbé-ayé tí ó gbé nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà ó dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọn ń bèèrè láàrin ìjọ nípa ìpadàbọ̀ Kristi. Díẹ̀ ninu àwọn ìbéèrè náà nìwọ̀n yí: Bí onigbagbọ kan bá jáde láyé kí Kristi tó pada dé, ǹjẹ́ ó ní ìpín ninu ìyè ainipẹkun tí Kristi yóo mú bọ̀ nígbà tí ó bá pada dé? Ati pé nígbà wo gan-an ni Kristi yóo pada wá? Paulu lo anfaani àwọn ìbéèrè wọnyi láti bẹ̀ wọ́n pé kí wọn máa ṣe iṣẹ́ igbagbọ wọn lọ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, bí wọn ti ń fi ìrètí dúró de àkókò tí Kristi ń pada bọ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1
Ìdúpẹ́ ati ìyìn 1:2—3:13
Ẹ̀bẹ̀ fún ìgbé-ayé onigbagbọ 4:1-12
Ẹ̀kọ́ nípa ìpadàbọ̀ Kristi 4:13—5:11
Ọ̀rọ̀ ìyànjú 5:12-22
Ọ̀rọ̀ ìparí 5:23-28

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Tes Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa