I. Tes 4:1-12

I. Tes 4:1-12 YBCV

NJẸ li akotan, ará, awa mbẹ̀ nyin, awa si ngbà nyin niyanju ninu Jesu Oluwa, pe bi ẹnyin ti gbà lọwọ wa bi ẹnyin iba ti mã rìn, ti ẹnyin iba si mã wù Ọlọrun, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nrìn, ki ẹnyin le mã pọ̀ siwaju si i. Nitori ẹnyin mọ̀ irú aṣẹ ti a ti pa fun nyin lati ọdọ Jesu Oluwa. Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ́ nyin, pe ki ẹnyin ki o takéte si àgbere: Ki olukuluku nyin le mọ̀ bi on iba ti mã ko ohun èlo rẹ̀ ni ijanu ni ìwa-mimọ́ ati ni ọlá; Kì iṣe ni ṣiṣe ifẹkufẹ, gẹgẹ bi awọn Keferi ti kò mọ̀ Ọlọrun: Ki ẹnikẹni máṣe rekọja, ki o má si ṣe ṣẹ arakunrin rẹ̀ ninu nkan na: nitori Oluwa ni olugbẹsan ninu gbogbo nkan wọnyi, gẹgẹ bi awa ti kilọ fun nyin tẹlẹ, ti a si jẹri pẹlu. Nitori Ọlọrun kò pè wa fun ìwa ẽri, ṣugbọn ni ìwamimọ́. Nitorina ẹnikẹni ti o bá kọ̀, ko kọ̀ enia, bikoṣe Ọlọrun, ẹniti o fun nyin ni Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ pẹlu. Ṣugbọn niti ifẹ awọn ará, ẹ kò tun fẹ ki ẹnikẹni kọwe si nyin: nitori a ti kọ́ ẹnyin tikaranyin lati ọdọ Ọlọrun wá lati mã fẹ ara nyin. Nitõtọ ẹnyin si nṣe e si gbogbo awọn ará ti o wà ni gbogbo Makedonia: ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, pe ki ẹnyin ki o mã pọ̀ siwaju si i; Ati pe ki ẹnyin ki o mã dù u gidigidi lati gbé jẹ, lati mã gbọ ti ara nyin, ki ẹ mã fi ọwọ́ nyin ṣiṣẹ, gẹgẹ bi awa ti paṣẹ fun nyin; Ki ẹnyin ki o le mã rìn ìrin ẹ̀tọ́ si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ le má ṣe alaini ohunkohun.