Awọn Filistini si ja, nwọn si lé Israeli, nwọn si sa olukuluku sinu ago rẹ̀: ipani si pọ̀ gidigidi, awọn ẹlẹsẹ ti o ṣubu ninu ogun Israeli jẹ ẹgbãmẹdogun.
Nwọn si gbà apoti ẹri Ọlọrun: ọmọ Eli mejeji si kú, Hofni ati Finehasi.
Ọkunrin ara Benjamini kan sa lati ogun wá o si wá si Ṣilo lọjọ kanna, ti on ti aṣọ rẹ̀ fifaya, ati erupẹ lori rẹ̀.
Nigbati o si de, si wõ, Eli joko lori apoti kan lẹba ọ̀na o nṣọna: nitori aiyà rẹ̀ kò balẹ nitori apoti Ọlọrun. Ọkunrin na si wọ ilu lati rohin, gbogbo ilu fi igbe ta.
Eli si gbọ́ ohùn igbe na, o sì wipe, Ohùn igbe kili eyi? ọkunrin na si yara wá o si rò fun Eli.
Eli si di ẹni ejidilọgọrun ọdun; oju rẹ̀ di baibai, kò si le riran.
Ọkunrin na si wi fun Eli pe, Emi li ẹniti o ti ogun wá, loni ni mo sa ti ogun na wá; o si bi i pe, Eti ri, ọmọ mi?
Ẹniti o mu ihin wá si dahun o si wipe, Israeli sa niwaju awọn Filistini, iṣubu na si pọ ninu awọn enia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji, Hofni ati Finehasi si kú, nwọn si gbà apoti Ọlọrun.
O sì ṣe, nigbati o darukọ apoti Ọlọrun, o ṣubu ṣehin kuro lori apoti lẹba bode, ọrun rẹ̀ si ṣẹ, o si kú: nitori o di arugbo tan, o si tobi. O si ṣe idajọ Israeli li ogoji ọdun.