ỌMỌ na Samueli nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli. Ọ̀rọ Oluwa si ṣọwọ́n lọjọ wọnni; ifihàn kò pọ̀.
O si ṣe li akoko na, Eli si dubulẹ ni ipo tirẹ̀, oju rẹ̀ bẹrẹ̀ si ṣõkun, tobẹ̃ ti ko le riran.
Ki itana Ọlọrun to kú ninu tempeli Oluwa, Samueli dubulẹ nibiti apoti Ọlọrun gbe wà,
Oluwa pe Samueli: on si dahun pe, Emi nĩ.
O si sare tọ Eli, o si wipe, Emi niyi; nitori ti iwọ pè mi. On wipe, emi kò pè: pada lọ dubulẹ. O si lọ dubulẹ.
Oluwa si tun npè, Samueli. Samueli si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi niyi; nitoriti iwọ pè mi. O si da a lohun, emi kò pè, ọmọ mi; padà lọ dubulẹ.
Samueli ko iti mọ̀ Oluwa, bẹ̃ni a ko iti fi ọ̀rọ Oluwa hàn a.
Oluwa si tun Samueli pè lẹ̃kẹta. O si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi niyi; nitori iwọ pè mi. Eli, si mọ̀ pe, Oluwa li o npe ọmọ na.
Nitorina Eli wi fun Samueli pe, Lọ dubulẹ: yio si ṣe, bi o ba pè ọ, ki iwọ si wipe, ma wi, Oluwa; nitoriti iranṣẹ rẹ ngbọ́. Bẹ̃ni Samueli lọ, o si dubulẹ nipò tirẹ̀.
Oluwa wá, o si duro, o si pè bi igbá ti o kọja, Samueli, Samueli. Nigbana ni Samueli dahun pè, Ma wi; nitori ti iranṣẹ rẹ ngbọ́.
Oluwa si wi fun Samueli pe, Kiyesi i, emi o ṣe ohun kan ni Israeli, eyi ti yio mu eti mejeji olukuluku awọn ti o gbọ́ ọ ho.
Li ọjọ na li emi o mu gbogbo ohun ti mo ti sọ si ile Eli ṣẹ: nigbati mo ba bẹrẹ, emi o si ṣe e de opin.
Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun.
Nitorina emi ti bura si ile Eli, pe ìwa-buburu ile Eli li a kì yio fi ẹbọ tabi ọrẹ wẹ̀nù lailai.
Samueli dubulẹ titi di owurọ, o si ṣi ilẹkun ile OLUWA. Samueli si bẹru lati rò ifihan na fun Eli.
Nigbana ni Eli pe Samueli, o si wipe, Samueli, ọmọ mi. On si dahun pe, Emi nĩ.
O si wipe, Kili ohun na ti Oluwa sọ fun ọ? emi bẹ ọ máṣe pa a mọ fun mi: ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si ọ, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ ba pa ohun kan mọ fun mi ninu gbogbo ohun ti o sọ fun ọ.
Samueli si rò gbogbo ọ̀rọ na fun u, kò si pa ohun kan mọ fun u. O si wipe, Oluwa ni: jẹ ki o ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀.
Samueli ndagba, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀, kò si jẹ ki ọkan ninu ọ̀rọ rẹ̀ wọnni bọ́ silẹ.
Gbogbo Israeli lati Dani titi o fi de Beerṣeba mọ̀ pe a ti fi Samueli kalẹ ni woli fun Oluwa.
Oluwa si nfi ara hàn a ni Ṣilo: nitoriti Oluwa ti fi ara rẹ̀ han fun Samueli ni Ṣilo nipa ọ̀rọ Oluwa.