I. Sam 23
23
Dafidi Gba Ìlú Keila Sílẹ̀
1NWỌN si wi fun Dafidi pe, Sa wõ awọn ara Filistia mba ara Keila jagun, nwọn si jà ilẹ ipakà wọnni li ole.
2Dafidi si bere lọdọ Oluwa pe, Ki emi ki o lọ kọlu awọn ara Filistia wọnyi bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe. Lọ, ki o si kọlu awọn ara Filistia ki o si gbà Keila silẹ.
3Awọn ọmọkunrin ti o wà lọdọ Dafidi si wi fun u pe, Wõ, awa mbẹ̀ru nihinyi ni Juda; njẹ yio ti ri nigbati awa ba de Keila lati fi oju ko ogun awọn ara Filistia?
4Dafidi si tun bere lọdọ Oluwa. Oluwa si da a lohùn, o si wipe, Dide, ki o sọkalẹ lọ si Keila, nitoripe emi o fi awọn ara Filistia na le ọ lọwọ.
5Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ si Keila, nwọn si ba awọn ara Filistia jà, nwọn si ko ohun ọsìn wọn, nwọn si fi iparun nla pa wọn. Dafidi si gbà awọn ara Keila silẹ.
6O si ṣe, nigbati Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sa tọ Dafidi lọ ni Keila, o sọkalẹ ton ti efodu kan lọwọ rẹ̀,
7A si sọ fun Saulu pe, Dafidi wa si Keila. Saulu si wipe, Ọlọrun ti fi i le mi lọwọ; nitoripe a ti dí i mọ tan, nitori o wọ inu ilu ti o ni ilẹkun ati ikere.
8Saulu si pe gbogbo awọn enia na jọ si ogun, lati sọkalẹ lọ si Keila, lati ká Dafidi mọ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀.
9Dafidi si mọ̀ pe Saulu ti gbèro buburu si on; o si wi fun Abiatari alufa na pe, Mu efodu na wá nihinyi.
10Dafidi si wipe Oluwa Ọlọrun Israeli, lõtọ ni iranṣẹ rẹ ti gbọ́ pe Saulu nwá ọ̀na lati wá si Keila, lati wá fọ ilu na nitori mi.
11Awọn agba ilu Keila yio fi mi le e lọwọ bi? Saulu yio ha sọkalẹ, gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ ti gbọ́ bi? Oluwa Ọlọrun Israeli, emi bẹ̀ ọ, wi fun iranṣẹ rẹ. Oluwa si wipe, Yio sọkalẹ wá.
12Dafidi si wipe, Awọn agbà ilu Keila yio fi emi ati awọn ọmọkunrin mi le Saulu lọwọ bi? Oluwa si wipe, Nwọn o fi ọ le wọn lọwọ.
13Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn to ẹgbẹta enia si dide, nwọn lọ kuro ni Keila, nwọn si lọ si ibikibi ti nwọn le lọ. A si wi fun Saulu pe, Dafidi ti sa kuro ni Keila; ko si lọ si Keila mọ.
14Dafidi si ngbe ni aginju, nibiti o ti sa pamọ si, o si ngbe nibi oke-nla kan li aginju Sifi. Saulu si nwá a lojojumọ, ṣugbọn Ọlọrun ko fi le e lọwọ.
15Dafidi si ri pe, Saulu ti jade lati wá ẹmi on kiri: Dafidi si wà li aginju Sifi ninu igbo kan.
16Jonatani ọmọ Saulu si dide, o si tọ Dafidi lọ ninu igbo na, o si gba a ni iyanju nipa ti Ọlọrun.
17On si wi fun u pe, Máṣe bẹru: nitori ọwọ́ Saulu baba mi kì yio tẹ̀ ọ: iwọ ni yio jọba lori Israeli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ̃ pẹlu.
18Awọn mejeji si ṣe adehun niwaju Oluwa; Dafidi si joko ninu igbo na. Jonatani si lọ si ile rẹ̀.
19Awọn ara Sifi si goke tọ Saulu wá si Gibea, nwọn si wipe, Ṣe Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ sọdọ wa ni ibi ti o to sa pamọ si ni igbo, ni oke Hakila, ti o wà niha gusu ti Jeṣimoni?
20Njẹ nisisiyi, Ọba, sọkalẹ wá gẹgẹ bi gbogbo ifẹ ti o wà li ọkàn rẹ lati sọkalẹ; ipa ti awa ni lati fi i le ọba lọwọ.
21Saulu si wipe, Alabukun fun li ẹnyin nipa ti Oluwa; nitoripe ẹnyin ti kãnu fun mi.
22Lọ, emi bẹ̀ nyin, ẹ tun mura, ki ẹ si mọ̀, ki ẹ si ri ibi ti ẹsẹ rẹ̀ gbe wà, ati ẹniti o ri i nibẹ: nitoriti ati sọ fun mi pe, ọgbọ́n li o nlò jọjọ.
23Ẹ si wò, ki ẹ si mọ̀ ibi isapamọ ti ima sapamọ si, ki ẹ si tun pada tọ mi wá, nitori ki emi ki o le mọ̀ daju; emi o si ba nyin lọ: yio si ṣe, bi o ba wà ni ilẹ Israeli, emi o si wá a li awari ninu gbogbo ẹgbẹrun Juda.
24Nwọn si dide, nwọn si ṣaju Saulu lọ si Sifi: ṣugbọn Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ wà li aginju Maoni, ni pẹtẹlẹ niha gusu ti Jeṣimoni.
25Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ iwá a. Nwọn si sọ fun Dafidi: o si sọkalẹ wá si ibi okuta kan, o si joko li aginju ti Maoni. Saulu si gbọ́, o si lepa Dafidi li aginju Maoni.
26Saulu si nrin li apakan oke kan, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ li apa keji oke na: Dafidi si yara lati sa kuro niwaju Saulu; nitoripe Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti rọ̀gba yi Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ka lati mu wọn.
27Ṣugbọn onṣẹ kan si tọ Saulu wá, o si wipe, iwọ yara ki o si wá, nitoriti awọn Filistini ti gbe ogun tì ilẹ wa.
28Saulu si pada kuro ni lilepa Dafidi, o si lọ ipade awọn Filistini: nitorina ni nwọn si se npe ibẹ̀ na ni Selahammalekoti, (ni itumọ rẹ̀, okuta ipinyà.)
29Dafidi ti goke lati ibẹ lọ, o si joko nibi ti o sapamọ si ni Engedi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Sam 23: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.